Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Citadel Global Community Church, ti awọn eyan tun n pe ni Latter Rain Assembly, Pasitọ Tunde Bakare, ti sọ pe Ọlọrun ti kẹyin patapata si ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari lorilẹ-ede Naijiria.
O loun n reti ki Aarẹ Buhari wa a gbe oun, gẹgẹ bo ṣe n le ẹmi awọn yooku kaakiri, nitori pe oun fẹ ki ogun ṣẹlẹ lorilẹ-ede yii. Ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii ni Pasitọ Bakare sọrọ naa lakooko to n waasu fawọn ọmọ ijọ rẹ.
“Agbara ko si lọwọ rẹ mọ, apaṣẹ lori ofo lasan lo jẹ bayii, ayafi awọn ti o fi sibẹ nikan. Ọfiisi to ga julọ lorilẹ-ede yii lasiko yii ni ọfiisi awọn araalu. Awọn ọmọ Naijiria yoo dide, ti wọn yoo si beere fun ẹtọ wọn.”
“Mo gbena woju ẹ ki o le gbiyanju lati na ọwọ rẹ wa sọdọ mi, gẹgẹ bi o ṣe n ṣe fawọn yooku, igba naa lo to maa mọ boya Ọlọrun lo ran mi niṣẹ, tabi pe agba ofifo lasan ni mo jẹ.
“Naijiria fun Naijiria; akooko lati gba orilẹ-ede yii la ti de; ijọba ko le gba wa la, Awọn ọmọ Naiijiria ni lati dide beere fun ohun to jẹ ẹtọ wọn.
“Kuro lọna mi, kuro lọna mi, ikilọ igbẹyin ree. Mo nifẹẹ rẹ, mo bọwọ fun ẹ, ohun gbogbo ni mo ṣe lati ri i pe nnkan ṣiṣẹ fun ẹ, ṣugbọn 'se lo yiju lodi si mi, bẹẹ lo si keyin si Ọlọrun, kuro lọna mi.”
Siwaju si i ni Pasitọ Bakare tun loun sọ fun Buhari lọdun 2014 wi pe yoo di Aarẹ, toun si sọ bi yoo ṣe ṣẹlẹ fun un, ṣugbọn to ni ẹnu toun fi sọ fun un nigba naa ti wa a di ẹnu to n run bayii.
Bakare loun ko ṣetan lati ṣe ipade pọ pẹlu Aarẹ Buhari mọ, nitori pe ogun ti n bọ.
"Mi o jiroro pẹlu ẹnikẹni mọ, nitori pe, ogun ni."
Bẹ o ba gbagbe, Aarẹ Buhari ati Pasitọ Bakare ni wọn jọ gbe apoti ibo Aarẹ lọdun 2011, bẹẹ lo tun ṣatilẹyin Buhari lọdun 2015, ṣugbọn ti awọn mejeeji ko gba ti ara wọn mọ bayii.
No comments:
Post a Comment