Ìgbòho kọ lẹ́tà ẹ̀rí ọkàn sí Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí, bẹ́ẹ̀ ló tún ní kó bẹ̀ru Ọlọ́run - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 26, 2021

Ìgbòho kọ lẹ́tà ẹ̀rí ọkàn sí Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí, bẹ́ẹ̀ ló tún ní kó bẹ̀ru Ọlọ́run


Ki i ṣe tuntun mọ pe oni, ọjọ Aje, Mọnde ni olori ajijangbara ilẹ Yoruba lapapọ, Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho yoo foju ba ile ẹjọ ni Benin.

Loni kan naa lo kọ lẹta ẹri ọkan ranṣẹ si Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari nipa awọn ẹsun idaluru to fi kan an.

Ninu lẹta naa ti Ọgbẹni Tunde Ọdẹṣọla kọ lo ti ran Buhari leti nipa awọn iṣẹlẹ ikọlu awọn Fulani si awọn ọmọ Yoruba, paapaa awọn ọmọ ilu Igboho, nibi ti Sunday Adeyẹmọ funra rẹ ti wa.

O ni ko ranti daadaa wi pe oun (Buhari) wa lara awọn igbimọ to wa ba Gomina ipinlẹ Ọyọ nigba naa, Lamidi Adeṣina (Lam Adeṣina), nibi ti wọn ti tọwọ bọ iwe adehun, iyẹn lọsu kẹwaa, ọdun 2000.

Ẹkunrẹrẹ lẹta naa n bọ laipẹ, ẹ ku lọna

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI