Ilé ẹjọ́ to n gbọ ẹjọ ẹsun ti wọn fi kan Oloye Sunday Igboho lorilẹ-ede Benin ti sọ pe awọn nilo lati farabalẹ lati gbe ẹjọ naa yẹwo daadaa.
O ni ẹjọ naa ko ni le e pari lalẹ oni, Tọsidee, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
Aarọ ọla, ọjọ Ẹti, Furaidee ni igbẹjọ yoo tẹsiwaju, iyẹn bi ile ẹjọ ṣe sọ.
Agbejọ́rọ́ Oloye Sunday Adeyemo gẹgẹ bi a ṣe gbọ ṣàlàyé pe asiko ko tii to lati sọ̀rọ̀ lori igbẹ́jọ́ naa ṣugbọn oun gbagbọ́ pe didun lọ́san o so.
Agbejọ́rọ́ Ijoba naa ko ba awọ́n akọ́royin sọ́rọ̀.
No comments:
Post a Comment