Ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ l'Ógùn! So-Safe kó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ẹ̀ṣọ́ ààbò wọn síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 19, 2021

Ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ l'Ógùn! So-Safe kó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ẹ̀ṣọ́ ààbò wọn síta


Lojuna lati jẹ ki alaafia jọba lasiko idibo ijọba ibilẹ to fẹẹ waye kaakiri ipinlẹ Ogun lọjọ kẹrinlelogun oṣu yii, ileeṣẹ So-Safe Corps ti sọ pe ko din ni ẹgbẹrun mẹta awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ti wọn ṣetan lati da sita.

Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ naa, Ọgbẹni Mọruf Yusuf fi sita laipẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe ọga awọn, Sọji Ganzallo ti pari gbogbo eto naa.

O ni gbogbo awọn ẹgbẹrun mẹta naa ni wọn ti la idanilẹkọọ ara ọtọ kọja nipa bi wọn yoo ṣe ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo yooku lasiko idibo naa.

Siwaju si i lo sọ pe gbogbo ẹkọ to yẹ ki onikaluku wọn mọ lawọn ti fi ye wọn, daadaa, ati pe wọn ko gbọdọ ba ẹnikẹni ja tabi fa wahala, bi ko ṣe ki wọn ṣiṣẹ agbofinro araalu.

Bẹẹ lo ni awọn ti gbe awọn nọmba pajawiri to pe ni 09069392064, 08028286064, 08035479930 sita fun awọn lati ta wọn lolobo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI