Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ awọn gendekunrin mẹta kan ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju ole jija lọ lagbegbe Atan-Ọta, ti wọn si ti wa nibi ti wọn ti n ka boroboro.
AWIKONKO gbọ pe obinrin kan ti wọn pe ni Tọpẹ Alabi lawọn mẹtẹẹta lọ ka mọ inu ṣọọbu rẹ, ti wọn si fibọn, oogun abẹnugọngọ digun ja a lole owo to pọ diẹ, ti wọn si tun ko lara awọn ọja to n ta salọ.
Anu Ibikunle, ọmọ ọdun mejilelọgbọn; Rasheed Bisiriyu, ọmọ ọdún mejilelogun ati Adebọwale Dada, ọmọ ọdun marundinlọgbọn lawọn mẹtẹẹta ọhun.
Wọn ni agbegbe Oke-Ọrẹ to wa ni Atan-Ọta ni obinrin naa, Tọpẹ Alabi ti n ta warobo, pẹlu ọti ẹlẹrindodo loriṣiriṣi, nibẹ si ni wọn ti lọ ka a mọ pẹlu awọn nkkan ija oloro.
Lẹyin ti wọn gba gbogbo owo to pa lọjọ naa lọwọ ẹ, ni wọn tun ko lara awọn ọja rẹ salọ.
Bi wọn ṣe lọ tan la gbọ pe obinrin yii pariwo sita pe kawọn eeyan gba oun. Ariwo yii lo so ta awọn eeyan ji, ti wọn fi le wọn lọ, lẹyin o rẹyin lọwọ tẹ awọn mẹtẹẹta.
Lara awọn ẹlẹyinju aanu to wa nibẹ la gbọ pe wọn ranṣẹ pe awọn agbofinro, ti wọn si wa a ko wọn lọ teṣan.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti wa a sorpe iwadii ti bẹrẹ lori wọn, ati pe ọga awọn, Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn lọ foju wọn ba ile ẹjọ lẹyin iwadii.
No comments:
Post a Comment