Ibi tí ẹ fojú sí, ọ̀nà kò gbabẹ̀ rárá - Agbẹjọ́rò Ìgbòho tún tú àṣírí tuntun síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 23, 2021

Ibi tí ẹ fojú sí, ọ̀nà kò gbabẹ̀ rárá - Agbẹjọ́rò Ìgbòho tún tú àṣírí tuntun síta


Ọkan lara awọn agbẹjọro Oloye Sunday Adeyẹmọ t'awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho, Ibrahim David Salami, ti sọ pe ki i ṣe iwe irinna orilẹ-ede olominira Benin ni wọn ba lọwọ ọkunrin naa lasiko ti wọn daa duro ni papakọ ofurufu tọwọ ti tẹ ẹ.

O ni iwe irinna orilẹ-ede Naijiria ati ti Germany ni wọn ba lọwọ ẹ. Fun idi eyi, o ni ki i ṣe ẹsun ayederu iwe irinna ni wọn fi kan Oloye Sunday Igboho niwaju ile ẹjọ.
 
Salami sọrọ yii lakooko to n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan Igboho, ati nnkan to ṣee ṣe ko jẹ abajade ẹjọ naa.
 
“Irọ ni wi pe iwe irinna ilẹ olominira Benin ni wọn ba lọwọ Sunday Igboho nigba ti wọn mu.

“Iwe irinna ti ilẹ Naijiria ati ti ilẹ Germany lo wa lara ẹ lakooko ti wọn mu. Iyawo naa, iwe irinna ilẹ Germany lo wa tọwọ toun nibi ti wọn ti jọ ko wọn.”

2 comments:

  1. Alhamdulillahi robil alamin ,God will surely be with cheif Sunday ighoho because he is not a criminal

    ReplyDelete
  2. Lagbara olohun o lotoo Sunday igboho koni Ku sipo ika

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI