Gomina Bala Mohammed, tipinlẹ Bauchi laipẹ yii ti tu aṣiri awọn oloṣelu Abuja, paapaa lori bi wọn ṣe n wa iṣubu ẹ ni gbogbo ọna, to si tun jẹ ko di mimọ pe pupọ ninu wọn lo wa nidi ipenija to de ba eto aabo lorileede yii.
Mohammed to sọrọ naa nibi to pin ounjẹ ti owo rẹ to miliọnu marundinlaadọrin fawọn eeyan ti ko din ni ẹẹdẹgbẹta nilii Darazo, ijọba ibilẹ Darazo, ipinlẹ naa jẹ ko di mimọ pe awọn oloṣelu Abuja kọ ni yoo sọ igbeṣe toun fẹẹ gbe nipa ipada sipo naa lẹẹkeji.
O ni to ba wu oun lọkan, oun le gbe apoti Aarẹ orileede yii, ti ko si sẹni to le da oun duro, ati pe boun yoo ba pada si ipo Gomina lẹẹkeji wa lọwọ Ọlọrun Allah to da oun saye.
Siwaju si i, ninu ọrọ rẹ, lo tun ti sọ pe, awọn oloṣelu Abuja ko ni nnkan meji ti wọn fẹẹ fun awọn araalu, bi ko ṣe ki wọn maa wa ọna lati ba ijọba.
“Ẹ ma ṣe gbọ nnkan ti awọn oloṣelu Abuja n sọ, wọn ko ni nnkan ti wọn fẹẹ ṣe ju ki wọn maa ti awọn eeyan ṣubu lọ, wọn n wa iṣubu Bala Mohammed, Kauran Bauchi ni.
“Pẹlu ogo Ọlọrun, mo ti di gomina nipa tabi lai si ọwọ wọn nibẹ, ati pe sibẹ, maa pẹ laye bi Ọlọrun Allah ba ṣi n fun mi ni oore ọfẹ. Mo le lọ fun saa keji, bẹẹ si ni mo si le ma si laye mọ ko to asiko naa; mo tiẹ tun wa le du ipo aarẹ, ko si nnkan ti wọn fẹẹ ṣe. Mo mọ gbogbo nnkan ti wọn n ṣe patapata.
“Awọn oloṣelu Abuja ko ṣe nnkankan fun wa ju pe ki wọn maa da rukerudo silẹ lọ. Iwa ikorira ni wọn n mu idagbasoke ba. Mo mọ awọn agbaagba kan nipinlẹ yii to jẹ pe awọn ni wọn n ko awọn ọdaran wọle wa. Mo ṣi maa sọrọ nigba ti akooko ba to. A maa jẹ ki wọn mọ iru eeyan ti a jẹ, nitori pe a ko bẹru wọn.”
No comments:
Post a Comment