Fíìmù 'Ọkọ Ìyábọ̀' dá wàhálà ńlá sílẹ̀ fún Yọ̀mí Fábìyí, ló bá ń wá ojúrere Ìyábọ̀ Òjó káàkiri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 27, 2021

Fíìmù 'Ọkọ Ìyábọ̀' dá wàhálà ńlá sílẹ̀ fún Yọ̀mí Fábìyí, ló bá ń wá ojúrere Ìyábọ̀ Òjó káàkiri


Bo tilẹ jẹ pe gbajugbaja oṣere nni, Yọmi Fabiyi ti n wa gbogbo ọna lati bẹ oṣerebinrin ẹgbẹ ẹ lori ọrọ ifipabanilopọ ti wọn fi kan Ọgbẹni Ọlanrewaju James Omiyinka, Baba Ijẹṣa ati fiimu Ọkọ Iyabọ to gbe jade, sibẹ ileeṣẹ to n ri sọrọ idajọ araalu nipinlẹ Eko, Lagos State Directorate of Public Prosecution (DPP) ti sọ pe ọkunrin naa ti tapa si ofin ofin ati ilana ile-ẹjọ.
 
Ko si nnkan to jẹ ki DPP sọ eyi sita lọjọ Aje, Mọnde ana, bi ko ṣe ti fimmu 'Ọkọ Iyabọ' ti Yọmi Fabiyi ṣe, to si gbe e jade.
 
Fabiyi ninu fiimu ọhun ni wọn lo darukọ gbogbo awọn tọrọ kan ninu ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijẹṣa, ti wọn loo fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla ti Princes gba tọ laṣepọ.
 
~Wo fiimu ỌKỌ IYABỌ lori YouTube~
 
Ọlayinka Adeyẹmi to jẹ agbẹjọro DPP sọ niwaju ile ẹjọ lanaa, ọjọ Aje, Mọnde wi pe gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ lori ọrọ naa patapata, ni Fabiyi fi ṣe fiimu 'Ọkọ Iyabọ', eyi to lo lodi s'ofin ile ẹjọ, tawọn si ni lati pe e lẹjọ.
 
Siwaju si i lo tun sọ pe fiimu naa sọ fun gbogbo aye wi pe Baba Ijẹṣa ko mọ nnkan nipa ẹsun ti wọn fi kan an, ati pe ṣe ni wọn fẹẹ ba a lorukọ jẹ nitori ajọṣepọ Baba Ijẹṣa ati Princes ti ko dan mọnran mọ.
O wa a n i ṣe ni Yọmi Fabiyi n sa kaakiri bayii, idi ti ko fi yọju sile ẹjọ, to fi ran awọn aṣoju rẹ wa lati mọ bi nnkan ṣe n lọ.
 
Lẹyin eyi ni agbẹjọro baba Ijẹṣa, Dada Awoṣika sọ fun ile-ẹjẹ wi pe fiimu ti Yọmi Fabiye gbe jade, ko ni nnkan ṣe pẹlu ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijẹṣa, bi ko ṣe ọrọ aawọ to wa laaarin ọkunrin naa ati Iyabọ Ojo.

Onidajọ Oluwatoyin Taiwo nigba toun naa n sọrọ sọ pe oun yoo ṣe iwadii ohun ti fiimu naa da le lori, lati mọ boya Yọmi Fabiyi ni ẹjọ lati jẹ tabi bẹẹ kọ.

AWIKONKO gbọ pe gbogbo ọna bayii ni Yọmi Fabiyi n wa lati bẹ Iyabọ Ojo, ki wọn le pari ẹjọ naa, ki nnkan ti wọn n ro ma ba a ṣẹlẹ, ṣugbọn ti wọn sọ pe oṣerebinrin naa ko fi oju silẹ fun un.

Wọn ni oriṣiriṣi ọrọ to dun ni Fabiyi n kọ nipa Iyabọ Ojo sori ikanni ayelujara kaakiri lati fi wa ojurere rẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI