Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe ilana eto ẹkọ tawọn ba nilẹ nigba ti wọn gba ijọba kan wọn lominu oupọ, to si ni ina eto ẹkọ ipinlẹ naa ti jo ajorẹyin gidigidi.
Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq lo sọrọ naa laipẹ yii, to si loun ti ṣetan lati gba oniruuru amọran lati ọdọ awọn eeyan, paapaa awọn ọjọgbọn, to fi mọ awọn alẹnulọrọ lẹka eto ẹkọ kaakiri ipinlẹ naa, eyi to le mu idagbasoke ba ẹkọ.
Gomina sọ pe lara awọn adojukọ toun ṣakiyesi wi pe wọn n dojukọ eto ẹkọ ni: owo, aisi igbega fawọn olukọ, yara ikawe ti ko si, awọn olukọ ti ko to nnkan, aisi awọn ọkọ, awọn nnkan to le mu ori olukọ ati akẹkọọ wu, atawọn mi in.
O ni kawọn to le yanju awọn iṣoro wọnyi, afi ki wọn kede ijọba pajawiri lori eto ẹkọ, to si n pe awọn ọjọgbọn lati wa a fi agbekalẹ wọn to le mu idagbasoke ba eto ẹkọ ipinlẹ naa.
Eyi la gbọ pe o jẹ ki wọn gbe eto kan ti wọn pe ni 'Kwara Education Futures Summit' kalẹ. Eto naa si la gbọ pe yoo bẹrẹ lọjọ karun-un, oṣu kẹjọ, ọdun yii.
Gbogbo awọn to ba fee kopa ni wọn lanfaani lati forukọsilẹ lori ikanni ayelujara ti wọn ti ya sọtọ yii, iyen www.KwaraEducationFutures.com ati fun alaye lẹkunrẹrẹ.
Wọn nigba ti wọn yoo ba fi bẹrẹ ilana eto ẹkọ tuntun, pupọ awọn ipinlẹ to wa lorileede Naijiria ni yoo maa wo wọn bi awokọṣe, ati pe wọn yoo ṣiṣẹ takuntakun lati le wọn ba.
No comments:
Post a Comment