Àṣírí nla mi in lo tun ti tu bayii nipa bi ọwọ ṣe tẹ olori ajijangbara ominira ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho ati iyawo ẹ, Arabinrin Rọpo Adeyẹmọ ni papakọ ofurufu orilẹ-ede olominira Benin.
AWIKONKO gbọ pe Igboho ti lọ gba kaadi irinna miran ti yoo fi kuro lorilẹ-ede Benin lọ si Germany, nibi to tun ti niwe igbelu.
Wọn nibi to fiwe iwe irinna naa han ẹni ti yoo dari rẹ lọ sinu ọkọ baluu ti yoo gbe e lalẹ ijẹta, Mọnde ni ẹni naa fura wi pe Igboho ti wọn n wa lo yọju yii. Ibi ti wọn ti jọ n fa ọrọ yii la gbọ pe oun pẹlu iyawo rẹ ti poora, to si salọ kuro nibẹ ki ọwọ ma ba a tẹ ẹ.
Nigba ti wọn ri i pe wọn ko mọ boun pẹlu iyawo rẹ ṣe rin in, lo mu ki wọn pe awọn agbofinro, ti wọn si pinnu ọna ti wọn yoo gba mu. Nibẹ la gbọ pe wọn ti gbe oṣiṣẹ kan to n ṣeto iwe irinna dide wi pe ko lọ tan wọn wa.
Oṣiṣẹ to n ṣeto iwe irinna ni papakọ ofurufu naa lo lọ ba Igboho ati iyawo ẹ nibi ti wọn farapamọ si wi pe wọn ti yanju ọrọ naa, ki wọn si wa lọ wọ ọkọ baluu lati maa lọ si Germany ti wọn n lọ.
Bi wọn ṣe pada sibẹ la gbọ pe awọn agbofinro ti raga bo wọn, ti wọn si ko wọn.
Iroyin mi in to tun tẹ wa lọwọ ni pe lẹta ikọkọ kan ni aṣoju Naijiria si orílẹ̀-èdè olómìnira Benin, Ajagunfeyinti Tukur Buratai wi pe ki wọn wa lojufo nipa ọkunrin ti wọn n pe ni Igboho.
Lẹta yii ni wọn fi ranṣẹ sawọn oṣiṣẹ eleto aabo kaakiri, eyi si ni wọn ri, ti wọn fi da a mọ pe oun ni ẹni ti wọn n wa, iyẹn nigba to de papakọ ofurufu Cadjèhoun to wa ni Kutọnu.
Ṣaaju asiko yii ni ijọba Naijiria ti kede si awọn oṣiṣẹ aṣọbode mejeeji, iyẹn kọsitọọmu ati imigireṣan pe ki wọn mu Igboho silẹ nibikibi ti wọn ba ti ri i, wi pe o fẹẹ salọ kuro lorilẹ-ede yii.
Yatọ si eyi, ijọba apapọ tun ti sọ fawọn oṣiṣẹ eleto aabo lagbegbe Iwajọwa, Ṣaki West, ijọba ibilẹ Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, iyẹn ilu to tun sunmọ Benin wi pe o ṣee ṣe ki Igboho fẹẹ gba ibẹ salọ, nitori naa ki wọn wa ni ifura.
A gbọ pe bi Igboho ṣe gba awọn agbegbe yii kọja lai jẹ kawọn agbofinro ri i, lati le mu ko ye ẹnikẹni, ko to di pe o wọ Benin lati babẹ wọ Germany.
Wọn lawọn kan lo ta ijọba Naijiria lolobo wi pe o ṣee ṣe ki Igboho gbiyanju lati fẹẹ gba Benin salọ si Germany, eyi lo jẹ ki wọn lo Buratai gẹgẹ bi irinṣẹ lati mu.
AWIKONKO tun gbọ pe loju ẹsẹ ti wọn ti mu Igboho lawọn kan ti dide wi pe wọn ko ni jẹ ki wọn gbe e kuro nibẹ, bi ko ṣe pe ki wọn fi silẹ lati jẹ ko maa lọ si Germany to n lọ. Ero naa pọ lori awọn agbofinro yii debi wi pe wọn sare ranṣẹ si Tukur Buratai lati da si i.
Buratai ni wọn loo sọ fun wọn pe wọn ko gbọdọ fi silẹ, bi ko ṣe pe ki wọn maa gbe e pada bọ wa si Naijiria.
Gbogbo igbiyanju wọn lati jẹ ki wọn gbe Igboho pada wọ Naijiria la gbọ pe o ja si pabo, eyi ti wọn lo jẹ kawọn ọlọpaa agbaye, iyẹn Interpol gbe oun pẹlu ẹ lọ si ahamọ wọn.
Koda, a gbọ pe ijọba Germany naa ti n da si ọrọ yii wi pe ki wọn fi iyawo Igboho silẹ, nitori pe ọmọ wọn ni, ti wọn si ni o ṣee ṣe ki wọn gbe Igboho wọ Naijiria lonii, Wẹsidee.
Bakan naa ninu iroyin mi in, olori awọn agbẹjọro fun Igboho, Oloye Yọmi Alliyu ti pariwo síta wi pe ṣe ni awọn ọlọpaa agbaye, International Criminal Police Organisation, Interpol de Sunday Igboho ni ṣẹkẹṣẹkẹ mọlẹ sinu ahamọ wọn, ti wọn si n fiya jẹ ẹ.
O nigba toun n ba Igboho sọrọ, ṣe lo n sunkun bi ọmọ ikoko wi pe wọn ti fẹẹ pa oun danu, pẹlu ijiya ti wọn fi n jẹ ẹ.
Alliyu sọ pe ahamọ ọtọọtọ ni wọn fi Igboho ati iyawo ẹ, Rọpo si ni Kitọnu.
"Wọn dee mọlẹ ninu ẹwọn ti wọn fi si ni Kútọnu. Ija waye ni papakọ ofurufu lanaa nigba ti wọn mu.
"Wọn fi nnkan gba a lọwọ, wọn tun dee ni ṣẹkẹṣẹkẹ, inu inira ati irora lo wa, to n sunkun bi ọmọ ikoko nigba ti mo pe e, mo n gbọ ọ ketekete.
"Ọtọ ni sẹẹli ti wọn fi iyawo Igboho si, wọn ko de oun ni ṣẹkẹṣẹkẹ. Igboho n sunkun, iyawo rẹ naa n sunkun gidigidi. Adura wa ni pe wọn ko san owo fẹnikẹni lati pa a. Ẹ ko le eeyan sinu sẹẹli, ki ẹ tun de ẹni naa.
"Wọn mọ pe wọn ti ṣee leṣe, wọn ko si tọju ẹ, tabi ki wọn gbe e lọ si ọsibitu. A gbọ pe wọn fẹẹ foju ẹ ba ile ẹjọ, ṣugbọn mi o mọ bo ṣe fẹẹ ṣẹlẹ."
No comments:
Post a Comment