Awọn Boko Haram ati ISWAP ti fi fọto ati kaadi idanimọ awọn mẹrin kan ti wọn jẹ oṣiṣẹ ologun ati agbofinro ti wọn jigbe lopin ọsẹ to kọja yii han sita, nibi ti wọn ti n sọ pe ko sẹni to le gba wọn kuro lọwọ wọn.
Opopona Damaturu si Maiduguri la gbọ pe wọn ti ji awọn meji gbe, nigba ti wọn ji awọn meji yooku gbe loju ọna Kano lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii.
Ṣọja meji, Bello Abubakar ati Lpcl Oyediran Adedọtun, to fi mọ Mai Lalle ati Mustapha, tawọn jẹ agbofinro nipinlẹ Yobe, lawọn eeyan naa.
Funra awọn Boko Haram yii ni wọn gbe fọto awọn ti wọn jigbe naa sita fun ijọba Naijiria lati ri.
Titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan lawọn Boko Haram naa ko ti i pe ẹnikẹni yala, lori bi wọn yoo ṣe gba awọn eeyan naa silẹ kuro lahamọ wọn.
A gbọ pe ilu Maiduguri ni Mai Lalle ati Mustapha n lọ ki wọn too ji wọn gbe, nigba ti awọn ṣọja meji naa n lọ si ilu Kano, ki wọn too kagbako.
No comments:
Post a Comment