Ẹ wo Esther, Arẹwà ọmọ ogún ọdún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agbẹjọ́rò - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 29, 2021

Ẹ wo Esther, Arẹwà ọmọ ogún ọdún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agbẹjọ́rò


Ọmọbinrin ti ẹ n wo yii ni wọn n pe ni Esther Chukwuemeka, ọmọ ogun ọdun, ti wọn loo ṣẹṣẹ di ọkan lara awọn agbẹjọro lorilẹ-ede Naijiria.
 
Laipẹ yii ni wọn loo pari idanwo aṣekagba rẹ, to si yege daadaa.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ nipa Esther ni pe, ọmọ ọdun mẹtala lo wa, to ti pari ileewe girama rẹ, ṣugbọn ijọba orilẹ-ede yii ko gba a laaye lati wọ ileewe giga.
 
Eyi ni wọn loo jẹ ki baba rẹ mu kuro ni Naijiria lati le lọ kawe loke-okun. Bo si ṣe kawe tan, lo pada wa si Naijiria lati kawe nipa agbẹjọro.
 
Bi esi idanwo naa ṣe jade sita, lawọn eeyan ti bere si i ki i ku oriire, nitori pe o yege kọja afẹnuroyin.
 
Ọkan lara awọn adẹrinpoṣonu obinrin nni, Lepaciou Bọsẹ lo gbe e sori ikanni Insitagiraamu rẹ, nibi to ti n ki Esther ku oriire naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI