Wẹrẹ bayii ni iroyin iku ọkan lara awọn gbajugbaja sọrọsọrọ niluu Eko, Oloye Dapọ Ọṣhin jade sigboro, eyi to ba pupọ awọn ololufẹ rẹ lọkan jẹ kọja sisọ.
Ẹjẹ riru la gbọ pe o ran Dapọ, ẹni to tun jẹ agba oloye niluu Eko, iyẹn Lagos Island laarọ oni, Abamẹta, Satide.
Dapọ to n sọrọ lori amohunmaworan, tẹlifiṣan ati redio ni wọn lo ti pẹ ti aisan naa ti n ba a finra, to si jẹ pe gbogbo igba lo n gba itọju lọsibitu, ko le gbadun.
Ọsibitu LUTH, iyẹn Lagos University Teaching Hospital LASUTH to wa ni Ikeja, niluu Eko la gbọ pe o ku si.
No comments:
Post a Comment