Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lanaa, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii ti bura fun gbogbo awọn oludije to jawe olubori sawọn ipo alaga, igbakeji alaga ati kansẹlọ kaakiri ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ naa.
Opin ọsẹ to kọja ni eto idibo sawọn ipo kaakiri ijọba ibilẹ waye, niti ti ajọ eleto idibo ipinlẹ Ogun, OGSIEC ti kede gbogbo awọn oludije sipo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi awọn to jawe olubori.
Gbagede Arcade Ground, to wa ni Oke Mọsan, Abẹokuta ni eto ibura yii ti waye, nibi ti gbogbo awọn agbaagba nidi oṣelu, alẹnulọrọ lawujọ, to fi mọ awọn ọba alaye kaakiri ipinlẹ naa ti peju-pesẹ.
Abiọdun gba gbogbo wọn lamọran wi pe ki wọn jẹ olotitọ, ki wọn si sunmọ awọn eeyan wọn nijọba ibilẹ ti wọn ti dibo yan wọn, bẹẹ lo ni ki wọn ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bo ti tọ, ati bo ti yẹ.
Diẹ ree lara awọn fọto bi eto naa ṣe lọ si:
No comments:
Post a Comment