BB, gbajúmọ̀ alága NURTW tó n ta òògùn olóró wọ gàù l'Ekiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 25, 2021

BB, gbajúmọ̀ alága NURTW tó n ta òògùn olóró wọ gàù l'Ekiti


Ọkan lara awọn gbajumọ alaga ẹgbẹ onimọto NURTW nipinlẹ Ekiti, Babatunde Babade lọwọ palaba rẹ ti segi bayii, to si ti n bẹbẹ fun oju aanu, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.

AWIKONKO gbọ pe Babatunde, ẹni ọdun marundinlaadọta ni alaga ẹgbẹ awọn onimọto nijọba ibilẹ Ijero, ipinlẹ naa. 
 
Babatunde pẹlu awọn meji kan, Ilesanmi Ṣọla, ẹni ọdun marundinlogoji ati Babajide Johnson, toun jẹ ẹni ọdun marundinlaadọta lọwọ palaba wọn jọ segi lọjọ Aiku, Sannde to kọja lọ, iyẹn ọjọ kejidinlogun, oṣu yii. Nnkan bi aago meji ọsan lọwọ tẹ wọn.
 
Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, to jẹ agbẹnusọ ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun ati egbogi oloro lorilẹ-ede yii, NDLEA fi sita, o ni asiko ti wọn n lọ siluu Ekiti lati ilu Akurẹ lọwọ tẹ wọn ninu mọto Mazda ti nọmba idanimọ rẹ jẹ JER194AE.

O ni iwọn kilogiraamu mejilelaadọta aabọ {52.5kilograms} egboogi oloro ti wọn pe ni Skunk ni wọn gba lọwọ wọn lasiko ti wọn da wọn duro.
 
Awọn kan la gbọ pe wọn ta oṣiṣẹ ajọ NDLEA lolobo, ti wọn fi lọ dena de wọn.
 
O lawọn oṣiṣẹ agbofinro ti kọkọ mu mọto naa pẹlu awọn meji, ṣugbọn ti aburo Babatunde raaye gbe mọto naa salọ. Baagi egboogi oloro {cannabis sativa} mẹjọ ọtọọtọ ni wọn ba ninu mọto ọhun nigba naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI