Bi gendekunrin ti ẹ n wo yii ba fi le gbadun, ti ara rẹ ya daadaa, ko tun jẹ gbiyanju tabi ronu lati jale mọ gbogbo ọjọ to kun fun un lati lo laye. Itan manigbagbe ni yoo si maa fi ọrọ rẹ pa fawọn ọmọ ati ọmọ-ọmọ ẹ nipa ọjọ ti ko le gbagbe laye.
Ilu kan ti wọn pe ni Jerusalẹmu, nitosi Kojokrom, Sekondi-Takoradi ni Western Region ni gendekunrin ti wọn pe orukọ rẹ ni Uncle yii ti ji batiri mọto pẹlu owo gbe, ko to di pe ọwọ tẹ.
Uncle pẹlu ọrẹ rẹ kan la gbọ pe wọn jọ n lọ lọjọ naa, ti wọn si ri mọto ti wọn gbe sẹgbẹ ọna. Nibẹ lawọn mejeeji ti ṣi mọto yii, ti wọn si ji owo to wa nibẹ ko, koda, ti wọn tun yọ batiri mọto.
Batiri mọto yii ni wọn n yọ lọwọ, tawọn fi kofiri wọn. Bawọn mejeeji ṣe ri i pe aṣiri ti tu, ni wọn ti ba ẹsẹ wọn sọrọ, ṣugbọn to jẹ pe Uncle nikan ni ọwọ pada tẹ.
Wọn lawọn ẹlẹyinju aanu ni wọn sare ranṣẹ sawọn obi rẹ, ki wọn to wa a gbe e lọ ọsibitu ti wọn ti n tọju rẹ lọwọ, titi di asiko ta a fi kọ iroyin yii tan.
Alubami ni wọn fi Uncle ṣe lọjọ naa, to si jẹ pe bi ki ba a ṣe awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn tete ba a bẹbẹ ni, boya ni wọn ko ba luu pa lọjọ naa, tabi ki wọn dana sun un, ko si ti gbagbe wi pe oun ti wa sile aye ri.
No comments:
Post a Comment