Aye o! Ina afẹfẹ gaasi tun pawọn eeyan danu n'Ijẹbu Ode, eeyan mẹwaa lo farapa yanna-yanna - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 5, 2021

Aye o! Ina afẹfẹ gaasi tun pawọn eeyan danu n'Ijẹbu Ode, eeyan mẹwaa lo farapa yanna-yanna


Ariwo ikunlẹ lo gba ẹnu gbogbo awọn ara ilu Ijẹbu Ode, ipinlẹ Ogun laaarọ oni, ọjọ Aje, Mọnde nigba ti ina afẹfẹ gaasi deede bu gbau, to si pa awọn eeyan nipakupa.

Ikorita agbegbe kan ti wọn pe ni Fọlagbade to wa nilu Ijẹbu Ode ni ijamba naa ti waye, nibi tawọn ti ko din ni mẹwaa ti farapa yanna-yanna.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le fidi iye awọn to ba iṣẹlẹ naa rọrun mulẹ lasiko ta a kọ iroyin yii tan, ṣugbọn ohun ta a gbọ ni pe awọn mẹwaa lawọn oṣiṣẹ eleto aabo pannapanna ti ko lọ si ọsibitu jẹnẹra fun itọju.

A tun gbọ pe wọn ti ko awọn oku naa lọ si mọṣuari.

Oriṣiriṣi mọto ati ọkada, pẹlu dukia awọn eeyan lo ti ṣofo danu bayii.












No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI