AWIKONKO gbọ pe ẹwọn ogun ọdun gbako lo ti n kan ilẹkun bayii fun gbajugbaja 'olowo agbaye ori ikanni Instagiraamu' nni, Ramọn Abass, ti awọn eeyan tun mọ si Hushpuppi lori bo ṣe jẹwọ wi pe loootọ loun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.
Ẹsun gbigbe owo rin lọna ti ko ba ofin mu (money laundering) ni ijọba ilẹ Amẹrika fi kan Hushpuppi, ọmọ ọdun mejidinlogoji naa lọdun to kọja.
Bẹ o ba gbagbe, inakuna, ayekaye, aye fa-mi-lete-ki-n-tutọ ni Hushpuppi n jẹ kaakiri agbaye, eyi si lo jẹ ko di ilu-mọ-n-ka laaarin awọn ololufẹ rẹ.
Awọn ọlọpaa United Arab Emirates ati awọn ọlọpaa FBI, Federal Bureau of Investigation ni wọn rọwọ to ọkunrin naa niluu Dubai ninu oṣu kẹfa, ọdun 2020 to kọja, ko to di pe wọn gbe e lọ silẹ Amẹrika.
Yatọ si wi pe wọn fi ẹsun gbigbe owo kaakiri lọna ti ko tọ kan Hushpuppi, bẹẹ ni wọn tun fẹsun jibiti ori ayelujara kan an
Laipẹ yii la gbọ pe Hushpuppi kọ lẹta si ile-ẹjọ ilẹ Amẹrika, U.S. Central District Court of California, nibi to ti n bẹbẹ fun oju aanu, ẹyin to sọ pe loootọ loun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.
Agbẹjọro Hushpuppi, Louis Shapiro, ati igbakeji amofin agba ilẹ Amẹrika, Anil Antony, lo kọ iwe naa lọjọ kẹrin, oṣu yii.
Wọn ni bo ṣe ti gba wi pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa, o ṣee ṣe ko fi ẹwọn ogun ọdun gbara.
No comments:
Post a Comment