Àwọn dọ́kítọ̀ daṣẹ́ sílẹ̀ káàkiri Nàìjíríà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 31, 2021

Àwọn dọ́kítọ̀ daṣẹ́ sílẹ̀ káàkiri Nàìjíríà


Gbogbo awọn dọkitọ kaakiri orilẹ-ede Naijiria ti sọ pe ko si nnkan ti yoo da wọn duro lati da iṣẹ silẹ, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde to n bọ, iyẹn ọjọ keji, oṣu yii.

Ẹgbẹ awọn dọkitọ labẹ aburada Nigerian Association of Resident Doctors, NARD,  lẹyin ipade ti wọn ṣe ni wọn ti fẹnuko pe awọn ti pari ipinnu lati bẹrẹ idaṣẹsilẹ.

Wọn ni ijọba apapọ orilẹ-ede yii ti kuna lati mu ileri adehun ti wọn jọ ṣe lori iwe adehun ti wọn jọ tọwọ bọ lọgọrun ọjọ sẹyin.

Dọkitọ Uyilawa Okhuaihesuyi, to jẹ aarẹ ẹgbẹ naa, ẹni to ṣalaye lonii, Satide wi pe gbogbo eto lati da iṣẹ silẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI