Baale ile kan, Hasan Taiwo ni iroyin ti fi to wa leti wi pe o gun iyawo rẹ ọlọmọ mẹrin pa lagbegbe Lugbe to wa niluu Abuja, lọjọ Aiku, Sannde ijẹta yii.
Ohun ti a gbọ ni pe kinni ti wọn fi n fina sinu foonu, iyẹn ṣaja {Charger} la gbọ pe o da ija silẹ laaarin ololufẹ mejeeji yii, ti ọrọ naa si gba ibomiran yọ si wọn.
Ohun ta a gbọ ni pe iyawo Taiwo, Chibuzor Aloh, ni wọn lo n lo ṣaja ọkọ rẹ lati maa fi fina sinu foonu rẹ, eyi ti wọn ni ko gba aṣẹ lọwọ ọkọ rẹ.
Wọn ni bi Taiwo ṣe wọle, to ṣakiyesi wi pe Chibuzor n lo ṣaja oun, lo gba ọrọ naa si ibinu, to si bẹrẹ si i lu bi baagi abẹṣẹku-bi-ojo, titi to fi daku mọ-ọn lọwọ.
Awọn ọmọ wọn la gbọ pe wọn sare pariwo sita wi pe baba awọn ti lu iya wọn pa, eyi to jẹ kawọn ara adugbo sare lọ sibẹ lati rọmi le obinrin naa lori, to fi taji saye pada.
Lara awọn ara adugbo to bakọroyin sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ to kọja niṣẹlẹ ọhun waye. O ni ṣe ni taiwo lu obinrin naa daku, to jẹ pe awọn ara adugbo ti wọn da obinrin naa pada saye. Lẹyin eyi ni ọkọ naa jade lọ kuro nile.
“Igba to ya la gbọ pe obinrin naa ko lọ si ọsibitu lati lọ gba itọju to pe ye, to si jẹ pe inu ile lo ti n tọju ara rẹ. Ko sẹni to mọ ohunkohun to ṣẹlẹ si obinrin yii. Ṣugbọn lọjọ Satide, eyi to jẹ agbalagba ninu awọn ọmọ rẹ lo sare lọ pe awọn ara adugbo, to fi di pe wọn gbe e digbadigba lọ si ọsibitu.
“Gẹgẹ bi nnkan ti wọn sọ fun wa, ki wọn to gbe e debẹ lo ti dagbere faye. Wọn ni ọkọ rẹ ti ba ẹsẹ rẹ sọrọ. Wọn si ti gbe oku obinrin naa lọ si mọṣuari.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja, ASP Mariam Yusuf, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, to si jẹ ko ye wa pe iwadii ti bẹrẹ.
Iyen Koda oburu jai
ReplyDelete