Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress niluu Abuja ti gbe igbimọ dide ti yoo ṣakoso eto ipade gbogboogbo kaakiri awọn ipinlẹ to wa lorilẹ-ede yii.
Ana, Ọjọru, Wẹsidee ni ẹgbẹ oṣelu APC fi igbimọ naa lelẹ, lẹyin ti wọn bura fun gbogbo wọn tan ni olu-ileeṣẹ wọn to wa niluu Abuja.
Igbimọ yii la gbọ pe wọn yoo ṣakoso bi nnkan yoo ṣe lọ nibi eto ipade gbogboogbo naa, eyi ti ko ni jẹ ki wahala waye lawọn wọọdu kaakiri orilẹ-ede yii.
Akọwe igbimọ fidihẹ ti yoo ṣabojuto eto ipade gbogboogbo ẹgbẹ APC lapapọ, Sẹnetọ John James Akpanudoedehe, ni wọn loo bura fun wọn lorukọ alaga wọn, Gomina Mai Mala Buni.
Nibẹ lo ti gba gbogbo wọn lamọran pe ki wọn yago fun iwa magomago, ati iwa ẹlẹyamẹya to ṣee ṣe ko waye lakooko ipade gbogboogbo ọhun.
No comments:
Post a Comment