Agbẹjọro fun Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ ti ọpọ awọn eeyan mọ Sunday Igboho, Pẹlumi Ọlajẹngbesi ti sọ pe irọ ni iroyin to n lọ nigboro wi pe ọwọ awọn agbofinro lo tẹ ọkunrin naa, bi ko ṣe pe funra rẹ lo mọ ọn mọ fi ara rẹ silẹ fun ijọba orilẹ-ede yii.
Alẹ ana, ọjọ Aje, Mọnde, la gbọ pe ọwọ tẹ Igboho lorilẹ-ede ede olominra Benin lakooko to fẹẹ wọ ọkọ ofurufu salọ si ilu Germany.
Ọlanjẹngbesi lakooko to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe:
"Loootọ ni wọn ti mu Igboho, mo ti fidi rẹ mulẹ. A ti n gbe igbesẹ lati ri i daju pe o wa ni alaafia, nnkankan ko ṣe e. Ẹ mọ pe awọn DSS kede rẹ sita wi pe awọn n wa a. A kan gbagbọ ni pe wi pe Sunday Igboho ki i ṣe iṣoro. O jẹ ẹnikan to gbagbọ ninu wi pe ki awọn ọmọ Yoruba ati Naijiria lapapọ n gbe ni alaafia nibikibi ti wọn ba wa.
“Mo fẹẹ fi da a yin loju, mo si fẹ ki ẹ mọ pe wọn ko deede ri Sunday Igboho mu, bi ko ṣe pe o fẹẹ mọ ọn mọ fi ara rẹ silẹ fun ijọba. Bi ki ba a ṣe bẹẹ, wọn ko ṣa le deede mu bi wọn ṣe ri i mu yẹn. Ṣugbọn nitori igbagbọ rẹ wi pe o n fẹ ẹtọ gidi fawọn ọmọ Yoruba ati awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati le maa gbe ninu alaafoa, idi ree, to fi yọnda ara rẹ silẹ.
"Alẹ yii lo yẹ ko rin irin ajo lọ si orilẹ-ede Germany, ilu Kutọnu lo si fẹẹ gba lọ. O fẹẹ fi ilẹ Afrika silẹ lati Kutọnu to fẹẹ gba. Awọn agbofinro Kutọnu ni wọn rọwọ to o.
"Igbesẹ ti n lọ lati mu pada wa si Naijiria."
No comments:
Post a Comment