Bi gendekunrin ti ẹ n wo yii ba fi bọ ninu wahala afọwọfa to fa si ara rẹ lọrun yii, ti wọn tun pe e wi pe ko wa lọ ba wọn ji nnkan gbe, ko tun jẹ dahun, ayafi ti ọrọ rẹ ki ba a ṣoju lasan lo ku.
Nitori pe ẹni ṣango ba toju rẹ wọlẹ, ko ni ba wọn bu ọba koso ni ọrọ rẹ ri.
Agbado la gbọ pe gendekunrin naa lọ jigbe ninu oko oloko, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ.
Wọn ni bo ṣe ji agbado naa gbe, lo ko wọn sinu apo ṣaka to mu dani, to si gbe e salọ. Igba to de ile, to ku ko gbe agbado naa kalẹ lọrọ bẹyin yọ, ti ko si le sọ ọ kalẹ.
Gbogbo awọn ti wọn lo pe lati ba a yọ agbado naa ni ko ṣee ṣe fun wọn. Nigba to ti lo bi ọpọlọpọ wakati, ti ko le ri agbado naa sọ kalẹ, ni wọn loo pinnu lati gba teṣan ọlọ́pàá lọ lati fi to wọn leti.
Nibẹ lo si ti n bẹbẹ pe ki wọn wa lọ ba oun bẹ ẹni toun ji agbado rẹ gbe, lati le dariji oun, ati pe ọrun n wọ oun gidi gan an.
Agbegbe kan ti wọn pe ni Bunduri lorile-ede Ghana niṣẹlẹ yii ti waye.
Wọn ni okunrin yii ko ṣẹṣẹ maa jale, ati pe o ti pẹ to n ji agbado ẹni naa gbe, eyi ni wọn lo ṣee ṣe ko jẹ pe ẹni naa lo fi oogun sinu oko rẹ lati mu awọn to n ja a lole.
No comments:
Post a Comment