Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Abiọdun Ige Gani Adams ti sọ awọn idi pataki ti ko ṣe tẹlẹ Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho lọ sawọn iwọde to n ṣe kaakiri lati ja fun itusilẹ ati ominira ilẹ Yoruba.
Iba Gani Adams sọrọ naa lakooko to n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ laipẹ yii, nibẹ lo si ti sọ pe ipo toun di mu nilẹ Yoruba ati lorileede Naijiria ni ko jẹ koun darapọ mọ Sunday Igboho lati maa lọ fẹhonuhan kaakiri.
O ni ko yẹ ki wọn maa ri Aarẹ Ọnakakanfo nibi awọn iru iwọde ifẹhonuhan bẹẹ.
“Nigba ti Igboho bẹrẹ iwọde naa kaakiri ilẹ Yoruba, lotitọ, o fi orukọ mi sinu eto rẹ, mo si pe e, mo ṣalaye fun un wi pe mi o le darapọ mọ ọn ninu iwọde naa, mo ni ṣe o fẹ ki n ba orukọ ti Yoruba ti n bọwọ fun lati ọjọ pipẹ jẹ ni.
“Ọba awọn jagunjagun ni mi. Awọn ọba kan wa ti ipo wọn ju ti Aarẹ lọ. Ibi ti Yoruba duro si ree. Mo n bọwọ fun iṣẹṣe ni.
“Bo tilẹ jẹ pe Alaafin lo yan mi, sibẹ ipo mi wa fun gbogbo ọba patapata, ipo to wulo fun gbogbo ọba ilẹ Yoruba patapata ni.
“Bawo ni yoo ṣe ri, nigba ti ẹ ba gbọ pe nibi ti Aarẹ ti n fẹhonuhan, wọn waa fẹ tajutaju si i loju? Ṣe awọn eeyan le maa ti mi gẹgẹ bi wọn ṣe ti ọba awọn ologboni.
“Niru ipo ti mo di mu yii, ṣe ni mo ro pe o yẹ ki wọn maa gba amọran lọdọ mi, ki wọn si fi anfaani ipo mi ṣe atẹgun de awọn ibi ti wọn ba fẹẹ lọ, ki wọn si le ṣe aṣeyọri.”
No comments:
Post a Comment