Ijọba apapọ orileede Naijiria ti sọ balogun fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, John Mikel Obi di aṣoju awọn ọdọ lorileede yii, lati le jẹ kawọn ọdọ to ṣẹṣẹ n dide bọ le maa ri i gẹgẹ bi awokọṣe lati de ibi giga.
Papa iṣere apapọ orileede yii to wa ni Surulere l'Ekoo ni minisita fọrọ eto ere idaraya lorileede yii, Sunday Dare ti sọ ọ di mimọ pe awọn fẹran ọna ti Mikel gba ṣe awọn aṣeyọri ẹ.
O ṣapejuwe Mikel, agbabọọlu Chelsea naa tẹlẹ gẹgẹ bi ẹni ti awokọṣe rẹ ko le parẹ lailai, nitori to ti ṣi oju awọn eeyan si ere bọọlu alafẹsẹgba.
No comments:
Post a Comment