Ọgbẹni Rotimi Olumọ, to jẹ adari fẹgbẹ Oodua People Congress, OPC, ti Iba Gani Adams ti sọ pe gbogbo wahala to n waye niluu Igangan, atawọn ibi yooku ni Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, ọwọ ijọba lo ti n wa, nitori awọn Yoruba bọ, wọn ni amunkun ẹru ẹ wọ, o ni oke lẹ n wo, ẹ ko wo isalẹ.
O ni ko to di pe wahala ti ọjọ Sannde waye, oun kọkọ fẹẹ mẹnuba awọn nnkan to ti waye to rọ mọ eyi to ṣẹlẹ ọhun. Gẹgẹ bo ṣe wi, ni nnkan bi oṣu mẹta sẹyin lawọn oriṣi iṣẹlẹ n waye niluu Ibarapa atawọn ilu meje to yii po lori bawọn Fulani darandaran ṣe n ṣe wọn basabasa, ti wọn jere oko wọn, ti wọn ba wọn lopọ, ti wọn si tun ji wọn gbe.
O ni iṣẹ takuntakun lawọn OPC ipinlẹ Ọyọ, ti wọn wa lagbegbe naa ṣe, lati pese aabo fawọn eeyan to wa nibẹ. Lara n ni ti Wakili to ni awọn ọmọ lẹyin oun mu ninu igbo Ibarapa yii.
Olumọ tun sọrọ siwaju o ni, ‘’Wakili yii ni wọn fẹsun kan pe oun atawọn eeyan ẹ n da Ibarapa laamu, ti wọn jaye ọlọba, ṣe lawọn eeyan mi lọ doju ija kọ, ti wọn si mu, ti wọn si fa le awọn ọlọpaa lọwọ. Ṣugbọn siyalẹnu wa, awọn ọmọ wa mẹta ti wọn ṣiṣẹ ọhun lawọn ọlọpaa ti mọle, ti wọn si wa nibẹ, titi di akoko yii”.
O fikun ọrọ ẹ pe gbogbo akitiyan lawọn ti gba awọn eeyan yii silẹ lo ja si pabo, ti wọn ko ri nnkankan bawọn ṣe si.
O ni ibẹrubojo yii lo mu awọn eeyan oun ti wọn fi sa sẹyin pe awọn ko gbọdọ tun maa jiya nitori awọn ran araaalu lọwọ. O ni ẹdun ọkan lo si jẹ fawọn titi di akoko yii.
O ni oun tun wa lo akoko naa lati ke si awọn ọba alade gbogbo lati dide iranlọwọ si wọn. Bakan lo sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ pẹ awọn ko ni ohun ija oloro gidi lati maa fi koju awọn Fulani darandaran ọhun.
O ṣalaye pe bi wọn ba ri nnkan tawọn eeyan naa n gbe wa lati fi doju ija kọ wọn ni Ibarapa yii ẹru Ọlọrun yoo ba wọn, bẹẹ lo ni ijọba funra ẹ ko tii ṣetan lati ran awọn araalu lọwọ lori eto abo.
O ni pẹlu gbogbo nnkan to waye ọhun ni Igangan, awọn eeyan oun ko jẹ ki nnkan to ti ṣẹlẹ bu omi tutu si ọkan wọn, nitori pe latigba tawọn Fulani ọhun tun ti pada wa,ni wọn ti tu jade, ti wọn si gba ya wọn.
Olumọ tun fikun ọrọ ẹ pe ka ni ijọba ko mu awọn ti wọn mu yẹn ni, o ṣe e ṣe kawọn Fulani ọhun maa pada wa, nitori wọn ko tura silẹ tẹlẹ, amọ eyi to waye sẹyin lo mu wọn fa sẹyin.
Bẹẹ lo tun gboriyin fun Aarẹ Gani Adams, fun akitiyan ẹ lori eto- aabo, o ni aṣiwaju rere ni. O wa sọ pe loootọ lawọn ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn Amọtẹkun lori eto abo.
Ṣugbọn eyi to ṣe pataki ni pe kijọba ipinlẹ Ọyọ pese nnkan amuṣagbara lati fi le awọn Fulani ọhun lọ.
No comments:
Post a Comment