Afaimọ ni ki ọrọ naa ma pada di ohun tawọn eeyan ko ni i lero, bi Alaaji Lai Mohammed to jẹ minisita fọrọ iroyin, aṣa ati irin-ajo afẹ lorileede yii ko ba tete sọrọ lori ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan an.
Latigba ti Gomina ipinle Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti tu awọn aṣiri to da wahala ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ naa silẹ ni oriṣiriṣi awon aṣiri mi in tun ti bẹrẹ si i tu jade.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Kwara Political Front gbe jade lonii, ni wọn ti n pe Alaaji Lai Mohammed lati wa a ṣalaye bo ṣe na awọn owo, ati bo ṣe ṣe awọn dukia ti wọn lo lasiko ipolongo idibo ọdun 2011 ati 2019.
Wọn ni latigba ti wọn ti pari idibo ọdun 2011 ati 2019, ni Lai Muhammed ko pada wa a ṣalaye bo ṣe ṣe awọn dukia bi mọto, ọkada, kẹkẹ maruwa at'awọn mi in, ko si le wa ni akọsilẹ fun ọjọ iwaju.
Ninu atẹjade naa ti Aarẹ ẹgbẹ yii, Alaaji Abdullahi Mohammed bu ọwọ lu lo ti sọ pe gbogbo owo tawọn eeyan, paapaa awọn ẹlẹyinju aanu ko kalẹ fun ipolongo idibo ọdun 2011 ati 2019 ni Mohammed ko sapo ara rẹ, ti ko si ko wọn kalẹ fun ẹgbẹ naa.
Wọn ni bawọn eeyan ṣe n ko owo silẹ lati fi ran ẹgbẹ APC lọwọ fun idibo, ni Lai Muhammed n ko wọn pamọ, to si n ko diẹ diẹ jade bi ẹni pe oun lo n na awọn owo naa lapo ara rẹ.
O ni ki i ṣe owo nikan lawọn eeyan fi n ran ipolongo idibo ẹgbẹ lọwọ, bi ko ṣe mọto ati ọkada, to fi mọ awọn oniruuru nnkan iranwọ.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Niwọn igba ti Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ti sọ tiẹ nipa bi wọn ṣe ko owo naa, ẹgbẹ KPF naa n beere fun itọpinpin o ni kiakia lori bi wọn ṣe na awọn owo to wọle, eyi to gba ọdọ Alaaji Lai Mohammed wọle."
No comments:
Post a Comment