Ọrẹ ni Austin lọọ wo ki wọn to yinbọn pa-a lọdọ ọrẹ rẹ, lẹyin to pari idanwo aṣekagba rẹ ni fasiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 30, 2021

Ọrẹ ni Austin lọọ wo ki wọn to yinbọn pa-a lọdọ ọrẹ rẹ, lẹyin to pari idanwo aṣekagba rẹ ni fasiti


Adanu nla gba a niku gendekunrin to ṣẹṣẹ pari idanwo aṣekagba rẹ nileewe giga, fasiti tilu Benin, iyẹn University of Benin, Austin Izu.
 
Ọṣe to kọja yii la gbọ pe Austin pari idanwo aṣekagba rẹ ni fasiti naa. Ẹka ikẹkọọ Political Science, la gbọ pe ọmọkunrin naa wa.
 
Asiko ti wọn lo lọ wo ọrẹ kan, Walter Emaka nilegbe awọn akẹkọọ ti a mọ si Hostel, ni wọn sọ pe awọn agbebọn yawọ inu yara ọrẹ rẹ naa, ti wọn si yinbọn pa Austin danu, ṣugbọn ti wọn sọ pe ọrẹ naa raaye na papa bora pẹlu ọta ibọn lara.
 
Oju ọna Federal Girls College to wa ni Ugbowo la gbọ pe ilegbe awọn akẹkọọ naa wa. A gbọ pe oke ni Austin n gbe, nigba ti Walter n gbe ni isalẹ ilegbe wọn yii.
 
Ko pẹ ti wọn loo de ọdọ ọrẹ rẹ yii ni wọn sọ pe awọn agbebọn naa wọle tọ wọn lọ, ti wọn si yinbọn fun wọn.
 
Loju ẹsẹ lawọn eeyan ti lọ fiṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa BDPA, ti ẹkun Ugbowo leti.
 
Alukoro fasiti naa, Ọmọwe Benedicta Ehanire nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọ pe loootọ loun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn toun ko gbọ pe eeyan kankan ku nibẹ.
 
Obinrin naa sọ pe iroyin to tẹ oun lọwọ sọ pe Walter wa ni ọsibitu to ti n gba itọju lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI