Iyale ile kan to n tọmọ lọwọ lo ti pariwo sita wi pe kawọn eeyan gba oun lamọran wi pe ki ni koun ṣe sọrọ ọkọ oun to sọ omi ọyan oun di wara {miliiki} to fi n mu gaari lojoojumọ.
Obinrin naa ti a fi orukọ bo laṣiri lo sọrọ yii jade ninu atẹjiṣẹ to fi ranṣẹ sawọn ẹlẹyinju aanu.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe bi ere, bi awada loun fi ọrọ naa ṣe fun ọkọ oun lọjọ naa lọhun, ṣugbọn to sọ pe ọkọ oun ti sọ ọ di ojoojumọ bayii, to si lẹru n ba oun.
Obinrin yii sọ pe, ṣe ni ọkọ oun de lalẹ ọjọ naa, to sọ gaari lo wu oun lati mu, to si lo n beere pe ṣe ẹpa ati miliiki wa nile, ṣugbọn toun sọ pe ko si.
Siwaju si i lo sọ pe ṣe loun fi ọrọ naa dapara wi pe ṣe yoo fi omi ọyan oun ṣe miliiki, tawọn si rẹrin.
Igba ti obinrin yii sọ pe oun yoo fi lọ wo omi ọyan toun fun sinu ike fọmọ toun n tọ lọwọ lati mu, o loun ṣakiyesi wi pe o ti lọ silẹ. O nigba toun beere lọwọ ọkọ oun lo sọ pe nnkan toun lo niyẹn.
Latigba yii lo sọ pe ọkọ oun ti maa n beere fun omi ọyan oun lati maa mu ni gbogbo igba, eyi to lo maa n kan oun lominu pupọ.
Obinrin yii wa n beere wi pe kin ni koun ṣe, paapaa nigba ti ọmọ naa ko ba mu ọyan mọ, ti ko si omi mọ lọyan oun, ko si ma lọ maa wa ọmu obinrin mi in nita.
No comments:
Post a Comment