Ọfọ nla ṣẹ! Eyi ni bi Wolii TB Joṣhua ṣe ku lojiji, ni wọn ba ti ṣọọṣi rẹ pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 6, 2021

Ọfọ nla ṣẹ! Eyi ni bi Wolii TB Joṣhua ṣe ku lojiji, ni wọn ba ti ṣọọṣi rẹ pa


Bi ko ṣe ti i sẹni to le sọ pato nipa iru iku to pa gbajugbaja Ajihinrere agbaye nni, Pasitọ Temitọpẹ Balogun Joṣhua ti ọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye mọ si TB Joshua, ẹni to tun jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Synagogue Church of All Nations, to wa lagbegbe Ikọtun, niluu Eko.


Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laaarọ oni, a gbọ pe irọlẹ ana ni gbajugba iranṣẹ Ọlọrun naa jade laye lẹyin to pari isin ti wọn maa n ṣe ninu ṣọọṣi naa ni gbogbo irọlẹ ọjọ Satide, iyẹn Abamẹta.
 
Wọn ni bo ṣe pari iwaasu rẹ tan, to si bawọn eeyan sọrọ tan, lo sọ fun wọn pe oun fẹẹ lọ fun ara nisinmi diẹ nitori to rẹ oun lai mọ pe ọlọjọ ti de.
 
Nigba ti wọn reti Pasitọ TB Joṣhua lati dide lakooko to yẹ, ṣugbọn ti wọn ko ri i ko dide, ni wọn sọ pe amugbalẹgbẹ rẹ lọọ ba a lati beere alaafia rẹ, ṣugbọn ti wọn ni ko dahun.
 
Gbogbo bi wọn ṣe ni amugbalẹgbẹ naa n ba a sọrọ,  ni wọn sọ pe ko dahun, eyi ti wọn ni ki i ṣe bẹẹ tẹlẹ. Idi ree ti wọn loo fi sunmọ ọm lati gbe ọwọ rẹ soke, ti wọn si ni ṣe ni ọwọ naa lọ silẹ pada.
 
Bayii ni wọn ni ẹni naa ṣe pariwo sita, tawọn eeyan si sare sunmọ ọn. Loju ẹsẹ ni wọn ti pe dokita rẹ lati wa a ṣe ayẹwo fun un, ta a si gbọ dokita naa sọ pe ẹlẹmin ti gba a.
 
Lẹyin eyi ni wọn gbe ọkunrin naa lọ si mọṣuari ọsibitu Jẹnẹra to wa ni Isọlọ, nipinlẹ Eko.
 
Ko si nnkan meji to n ya awọn eeyan lẹnu nipa iku gbajugba ojiṣẹ Ọlọrun agbaye naa bi ko ṣe pe ayẹyẹ ipalẹmọ ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mejidinlọgọta rẹ to fẹẹ waye lọjọ kejila oṣu yii ni wọn n ṣe lọwọ ti iku wọle mu un lọ.
 
A gbọ pe gbogbo eto lo ti fẹẹ pari fun ayẹyẹ ọjọ ibi naa, toun funra rẹ si ti ṣe fọnran lati fi ki ara rẹ ku oriire ayẹyẹ ibi yii. Nigba to n sọrọ ninu fọnran naa lo sọ pe oun mọ idi tawọn ololufẹ oun kọọkan ko ṣe fẹẹ wa sibi ayẹyẹ ọjọ ibi, to si ni ọjọ ibi ṣi pọ rẹpẹtẹ lai mọ pe ọjọ iku rẹ ti sunmọ etile.
 
“Bi nnkan ṣe ri lasiko yii, ẹ le ti ṣakiyesi pe ko ni i rọrun fun mi lati ṣayẹyẹ ọjọọbi mi to sun mọle yii, nitori ilu ko fara rọ. Ọpọ awọn eeyan ti iba waa ba mi ṣayẹyẹ ko ni i le wa tori ọrọ aabo ti ko dara to loril-ede wa ati kari aye. A ri ibẹru wọn aniyan ọkan wọn. Mo mọ ọn lara bo ṣe dun wọn to, mo si mọ ero-ọkan wọn pẹlu. Tori naa, ẹ jẹ ka ya ọjọ yii sọtọ fun aawẹ ati adura. Ka ma si gbagbe awọn alaini ati mẹkunnu.”

Ọjọ kejila, oṣu kẹfa ọdun 1963 ni wọn bi Pasitọ TB Joṣhua. Ọmọ ipinlẹ Ondo ni, to si ti ṣiṣẹ iyalanu nla loriṣiriṣi lati tu awọn eeyan silẹ ninu igbekun ayeraye. Bo ṣe n ṣaanu awọn eeyan naa lo n ran awọn eeyan nileewe kaakiri agbaye.

Laarọ oni lawọn ọmọ ijọ Synagogue lọ lati ṣe isin, nibẹ lọpọlọpọ wọn ti bẹrẹ si i gbọ iroyin iku oludasilẹ ṣọọṣi naa, to mu ki gbogbo wọn bẹrẹ si i bu sẹkun.
 
Bawọn kan ṣe n gbe ara wọn ṣanlẹ naa lawọn kan n wa ẹkun mu bi i gaari, tawọn mi in si n fa aṣọ ya mọ ara wọn lara nitori bi iroyin iku naa ṣe ba wọn lojiji.
 
Wọn ni ṣe lawọn alaṣẹ ṣọọṣi naa ti ilẹkun pa nigba ti wọn lawọn kan dide lati mọ iru iku to pa TB Joṣhua, ṣugbọn ti ko sẹni to da wọn lohun.
 
Diẹ ree lara awọn fọto ohun to n ṣẹlẹ nibẹ lọwọlọwọ:
 
May be an image of standing and road

May be an image of one or more people, people walking, people standing and outdoors


May be an image of one or more people, people standing and road

May be an image of outdoors

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI