Ọgọọrọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako nni, Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Kwara ni wọn ti lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress bayii, pẹlu bi gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq ṣe tẹwọ gba wọn wọle sinu ẹgbẹ.
Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ PDP tẹlẹ naa ni wọn sọ pe awọn ko ṣe mọ, nitori pe ẹgbẹ naa ti su wọn, paapaa bi wọn ṣe sọ pe ko si otitọ kankan mọ ninu ẹgbẹ ọhun.
Abdulrasaq gbalejo wọn lati fi sami ayẹyẹ ijọba awa-ara-wa niluu Ilọrin ti ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.
Lara awọn to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC ni oludije sipo Aarẹ tẹlẹ ninu ẹgbẹ ACPN, Alhaji Ganiyu Galadimo, ati gbogbo awọn alaga kansu tẹlẹ lawọn ijọba ibilẹ mẹrẹẹrindinlogun ti wọn dibo yan labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Alhaji Abdullahi Samari, to sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun sọ pe ẹgbẹ ti tẹwọ gba awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ati ọmọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu miiran to le ni ẹgbẹrun mẹta jake-jado ipinlẹ Kwara, ti wọn si sọ pe, aseyori ti ẹgbẹ APC ẹka ti Kwara ti ṣe labẹ iṣejọba Abdulrahman Abdulrasaq lo wu awọn lórí tawọn fi darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu onitẹsiwaju ọhun.
No comments:
Post a Comment