Titi di asiko ta a pari iroyin yii ni ko ti i sẹni to le fidi rẹ mulẹ nipa iru iku to pa ọkan lara awọn akẹkọọ gbogboniṣe tipinlẹ Kadanu, iyẹn Kaduna State Polytechnic, Anas Abdullahi.
Ohun ta a gbọ ni pe ṣe ni Abdullahi sun, ti ko si ji saye mọ, iyẹn ni pe ṣe lo ti oju oorun de oju iku.
Ipele to gbẹyin (HND2) la gbọ pe Abdullahi wa ni ẹka ikẹkọọ imọ ẹrọ, ti awọn oloyinbo n pe ni Civil Engineering.
Alẹ ọjọ Ẹti, Furaide to kọja yii la gbọ pe ọmọkunrin naa sun ninu yara rẹ, to si jẹ pe asiko to yẹ ko ji laaarọ ana, Saide, Abamẹta, ko dide mọ.
Ori ikanni ayelujara ti fesibuuku lawọn ọrẹ rẹ ti tufọ iku ẹ, ti wọn si lawọn ko le gbagbe rẹ titi lai.
No comments:
Post a Comment