Ile ẹjọ giga t'ipinlẹ Ekiti to wa nilu Ado-Ekiti ti sọ pe ki wọn lọ yẹgi fun ọmọ ọdun mẹrinlelogun kan, Ṣọla Jẹgẹdẹ ti wọn loo ji foonu ati owo olowo gbe.
Ọgbọn ọjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2015 ni wọn ti fẹsun marun-un ọtọọtọ kan Ṣọla. Adugbo kan ti wọn pe ni Oda Ponna, Omuo Ekiti la gbọ pe ọmọkunrin naa ti jale yii.
A gbọ pe ṣe lo yọ ibọn, ada, atawọn nnkan ija oloro si Ibukun Ilesanmi, Ṣeun Ilesanmi ati Tọpẹ Ilesanmi, eyi to fi gba foonu olowo iyebiye ati owo lọwọ wọn.
Yatọ si eyi, wọn tun fẹsun ifipabanilopọ kan an.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Oluwatoyin Abọdunde da Ṣọla lare lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.
Bẹẹ lo sọ pe ki wọn lọ yẹgi fun Ṣọla titi ẹmi yoo fi bọ lara rẹ lori ẹsun kinni,, ekeji ati ẹkẹta ti wọn fi kan an.
No comments:
Post a Comment