Mo maa da owo idamẹwaa ati ọrẹ awọn ẹlẹṣẹ pada fun wọn - Pasitọ Kumuyi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 20, 2021

Mo maa da owo idamẹwaa ati ọrẹ awọn ẹlẹṣẹ pada fun wọn - Pasitọ Kumuyi


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Deeper Christian Life Ministry, Pasitọ Williams Fọlọrunṣọ Kumuyi ti sọ ọ sita gbangba wi pe oun ṣetan lati gbogbo idamẹwaa ati ọrẹ pada fun gbogbo awọn ẹlẹṣẹ inu ijọ naa.
 
Nibi iwaasu ọjọ isinmi ni Pasitọ Kunuyi ti sọrọ yii jade wi pe gbogbo awọn toun ba ri i wi pe wọn ṣi n da ẹṣẹ ninu ijọ naa loun yoo da gbogbo idamẹwaa ati ọrẹ wọn pada fun wọn lai ṣẹku ẹyọkan ṣoṣo.
 
Ojiṣẹ Ọlọrun naa sọ pe gbogbo awọn to ba ṣi n gbe ninu ẹṣẹ, ti wọn ko si ṣetan lati yiwa wọn pada kuro ninu ẹṣẹ, ṣugbọn ti wọn n fi owo wọn ran iṣẹ Ọlọrun lọwọ kan n fi owo wọn ṣofo danu lasan ni, nitori pe ko ni ipa kankan to n ko nigbesi aye wọn.
 
Kumuyi to ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa gbigbi ninu iwa mimọ tun sọ pe Ọlọrun ko nilo owo ẹlẹṣẹ, ti ko si ni idi kan ni pato ti ẹlẹṣẹ fi gbọdọ maa san idamẹwaa ati ọrẹ.
 
Ninu ọrọ baba yii, o sọ pe "Bi o ba jẹ ẹlẹṣẹ nibi, Ọlọrun ko nilo owo rẹ. Gbogbo owo to n fi silẹ fun Ọlọrun ko de ọdọ Ọlọrun. O kan n fi owo rẹ ṣofo danu lasan ni.
 
"Ki n sọ okodoro, bi mo ba mọ iye awọn ẹlẹṣẹ ti wọn wa nibi, ati iye owo ọrẹ ati idamẹwaa ti wọn ti san, mo maa yọ gbogbo ẹ, maa si daa pada fun wọn. Ọlọrun ko nilo ẹ, bẹẹ si ni ijọ naa ko nilo iru bẹẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI