Ma fọ, ọmọ iya mi, mo wa pẹlu ẹ fọdun mẹfa gbako - Emir Yashikira fọkan AbdulRazaq balẹ digbi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 1, 2021

Ma fọ, ọmọ iya mi, mo wa pẹlu ẹ fọdun mẹfa gbako - Emir Yashikira fọkan AbdulRazaq balẹ digbi


Emir tilu Yashikira, Alaaji Umar Sariki Usman ti sọ fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara wi pe ko lọ fi ọkan ara rẹ balẹ nitori digbi loun wa fun un lati ṣe ìṣàkóso ọdún mẹjọ.

O ni ọdún mẹfa to ku yii, awọn yoo jọ lo o ninu ayọ ati alaafia nla ni, nitori pe bo ṣe n bọwọ fún aṣa ati iṣẹṣe naa lo n tẹriba fawọn ọba atawọn oloye nipinlẹ naa.

Opin ọsẹ to kọjá ni Emir naa sọrọ yii, to si ni bi anfaani nla lo ṣi silẹ fun AbdulRazaq lati pada ṣe ìjọba ẹlẹẹkeji lọdun 2023.

Nibi ayẹyẹ ọdun kẹwàá lori ipo Emir ni ọrọ naa ti jade, to si ni bi onile ṣe fẹràn AbdulRazaq naa láwọn alejo to fi mọ awọn ọmọde, arúgbó ati ọdọ ko le gbagbe ipa to ti ko laaarin ọdún meji to de ipo naa titi lai.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI