'Aye lo n ṣe mi, ẹ dari jin mi' - Adeṣina to fipa ba iya arugbo, ẹni ọgọta ọdun laṣepọ l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 21, 2021

'Aye lo n ṣe mi, ẹ dari jin mi' - Adeṣina to fipa ba iya arugbo, ẹni ọgọta ọdun laṣepọ l'Ogun


Ṣe ni Adeṣina Adebọwale n wo pakopako lọgba ọlọpaa ipinlẹ Ogun lọjọ Aiku, Sande ana nigba tọwọ palaba ẹ segi, iyẹn nibi to ti n ko ibasun fun iya agbalagba, ẹni ọgọta ọdun kan.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Idanyin, ipinlẹ naa la gbọ pe Adeṣina ti lọọ ko ibasun fun iya arugbo naa karakara.
 
Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ sọ pe ṣe ni Adeṣina dee de wọnu yara mama naa ni nnkan bi aago mẹrin irọlẹ ana, lai kan ilẹkun. Bo si ṣe wọle lo ti ki iya yii mọlẹ ni tipatipa.

Wọn ni ko wo o pe iya yii ti dagba rara, to fi n ko ibasun fun un bi ẹni pe aṣẹwo lo n ba lopọ.

Ariwo ti wọn sọ pe mama yii pa lo mu kawọn to wa nitosi sare wọlẹ lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ, to si jẹ iyalẹnu nigba ti wọn ba Adeṣina nihooho ọmọluabi lori mama naa, to n laagun bi ọti to ti lo wakati mẹrinlelogun ninu ẹrọ amu-nnkan-tutu {firiiji} lai mu ina lọ.


Loju ẹsẹ lawọn eeyan ti bẹrẹ si i luu, tawọn kan si fẹẹ luu pa, ṣugbọn tawọn ẹlẹyinju aanu gba wọn lamọran lati mu lọ teṣan ọlọpaa lati fa a le wọn lọwọ.
 
Bawọn kan ṣe n sọ pe ọrọ Adeṣina, ẹni ogoji ọdun ki i ṣoju lasan, bẹẹ lawọn kan n sọ pe o ṣee ṣe ko fẹ fi mama naa ṣoogun owo ni.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti wa a sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ nnkan ti Adeṣina ri lọbẹ to fi waaru ọwọ, ati pe yoo tun lọ ṣalaye fun adajọ nigba tawọn ba foju ẹ ba ile ẹjọ lẹyin iwadii awọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI