Lẹyin to gba iwe ẹri, Olupo gbọpa aṣẹ lọwọ ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 25, 2021

Lẹyin to gba iwe ẹri, Olupo gbọpa aṣẹ lọwọ ijọba Kwara


Ẹsẹ ko gbero niluu Ajaṣẹ-Ipo nibi ti Ọba Ismail Yahaya Atoloye Alebioṣu, Olupo tiluu Ajaṣẹ Ipo ti gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bi ojulowo ọba ti ijọba fọwọ si.
 
Ana ti i ṣe Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq gbe ọpa aṣẹ le Ọba Alebioṣu lọwọ, nibi to ti n gba a lamọran lati mu idagbasoke ati iṣọkan ba ilu naa.

Nibẹ ni Gomina ti dupẹ lọwọ awọn araalu Ajaṣẹ-Ipo fun aduroti wọn, ati bi wọn ṣe fimọ ṣọkan lati yan Ọba Alebioṣu gẹgẹ bi ọba wọn, to si gba wọn lamọran lati fọwọsowọpọ fun idagbasoke ilu naa.

Alaga igbimọ fidihẹ fun ijọba ibilẹ Irẹpọdun, Kọmureedi Jide Oyinloye nigba to n sọrọ sọ pe asiko to dara gidi gan an ni wọn yan ọba naa, to si loun nigbagbọ pe asiko ọba naa yoo tu gbogbo ilu lara.
 
Ninu ọrọ tiẹ naa, ọba tuntun yii dupẹ gidigidi lọwọ awọn araalu ati ijọba ipinlẹ Kwara fun igbagbọ ti wọn ni lati yan an gẹgẹ bi ọba ati olori wọn. O ṣeleri wi pe gbogbo nnkan ti yoo ba gba loun yoo ṣe lati ri i pe awọn eeyan oun jẹ nafaani idagbasoke alailẹgbẹ.
 
o loun ṣetan lati ri i pe ifẹ ati alaafia to ti n jọba niluu naa tẹlẹ tubọ dagba si i pẹlu idagbasoke awọn nnkan amayedẹrun.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI