Ariwo ibanujẹ nla lo ṣẹyọ lagboole awọn sọrọsọrọ ori redio niluu Ibadan laaarọ oni, Sande, Aiku, nigba ti iroyin iku ọkan lara wọn jade sita.
Nnkan bi aago mọkanla aabọ alẹ ana, Satide la gbọ pe awọn agbebọn kan lọọ ka ọkunrin naa, Titus Badejọ, tọpọ awọn eeyan mọ si Ẹja Nla mọ, ti wọn si yinbọn pa a danu.
Ori redio Naija FM to wa niluu Ibadan la gbọ pe Ẹja Nla ti n ṣeto tẹlẹ, ko to di pe o kuro nibẹ, to si ni awọn ololufẹ rẹpẹtẹ.
Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ fi ye wa pe ile igbafẹ kan ti wọn pe '407 Club', eyi to wa ni Oluyọle Estate, Ibadan ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ọyọ la gbọ pe Ẹja Nla wa, nibi to ti lọọ ṣe faaji ara rẹ lasiko iṣẹlẹ naa.
Wọn ni ṣe ni Ẹja Nla bọ siwaju ita ile igbafẹ naa. Bo ṣe bọ sita ni wọn lawọn kan sunmọ ọn, ti wọn si yinbọn fun un. Ki i ṣe pe wọn yinbọn fun un nikan, wọn tun duro ti i, titi tẹmi fi bọ lara ẹ, ko to di pe wọn na papa bora.
Igba tawọn eeyan yoo fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ni ẹpa ko boro mọ, ati pe awọn to yinbọn fun un naa ti juba ehoro, ti ko si sẹni to da wọn mọ.
Ọsẹ to kọja yii naa la gbọ pe Titus Badejọ ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ogoji ọdun rẹ niluu Ibadan, nibi tawọn ololufẹ rẹ ti fi ifẹ han si i.
Ọkan lara awọn to mọ ọkunrin naa daadaa, Adepọju Ọmọniyi lo tufọ iku ọkunrin naa sita laaarọ oni, to si mu kawọn eeyan maa banujẹ kọja sisọ.
Folukọ Daramọla, oṣerebinrin naa tun gbe iroyin iku Badejọ sori ikanni ayelujara rẹ, to si loo dun oun gidi gan an wi pe ọkunrin naa ku lasiko yii.
No comments:
Post a Comment