Kaakiri agbaye lawọn ololufẹ gbajugbaja sọrọsọrọ ori redio nni, Kẹhinde Iṣọla ti pupọ awọn ololufẹ rẹ mọ si MC Van Garuba ti n fi atẹjiṣẹ loriṣiriṣi ranṣẹ si i, fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi to n ṣe lonii.
Bi wọn ba n darukọ awọn sọrọsọrọ ti wọn ṣẹṣẹ n dide bọ nipinlẹ Ogun lonii, ki wọn too darukọ marun-un, Van Garuba gbọdọ wa lara wọn, nitori ẹbun ti Ọlọrun fun un.
Ọkan pataki lara awọn ololufẹ iwe iroyin AWIKONKO ni Van Garuba, ẹni to kọ iṣẹ naa lọwọ Kọlawọle Adejojo, Kasnaty Sugar lọdun diẹ sẹyin.
A n fi asiko yii ki ọkunrin naa wi pe ẹmi yoo ṣe ọpọ ọdun laye ati laaye rere. Amin.
No comments:
Post a Comment