Ijọba Kwara ro awọn ileeṣẹ eleto aabo lagbara, ni idaamu ba de bawọn ọdaran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 25, 2021

Ijọba Kwara ro awọn ileeṣẹ eleto aabo lagbara, ni idaamu ba de bawọn ọdaran


Ọjọbọ, Tọsidee ana ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ro gbogbo awọn ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ naa lagbara nipa awọn nnkan ti yoo mu ki iṣẹ eto aabo rọrun, lati le gbogun ti iwa ọdaran.
 
Mọto iṣẹlẹ pajawiri aabo ogun, to fi mọ awọn aṣọ ayẹta ti ko lonka nijọba fi ta awọn ileeṣẹ eleto aabo naa lọrẹ, lojuna lati gbogun ti iwa ọdaran.
 
Lati nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin ni eto aabo orileede yii ti mẹhẹ, eyi to mu kawọn ijọba apapọ, ipinlẹ ati ijọba ibilẹ maa wa ọna lati gbogun ti awọn to n da alaafia ilu laamu.
 
Awọn mọto naa ni mọto ayọkẹlẹ mẹwaa, ati mọto Toyota Hilux mẹwaa ti wọn le sare daadaa ni ijọba ko kalẹ, ki eto aabo le tubọ kẹsẹjare.
 
Ninu Gomina Abdulrazaq, o sọ pe "A n fun awọn eleto aabo lawọn mọto wọnyii lati ro iṣẹ wọn lagbara. A ṣe bẹẹ lọdun to kọja, a si tun n ṣe bẹẹ lọdun yii, a n fi kun awọn mọto naa.
 
"Nnkan ti yoo maa tẹsiwaju ni. Ijọba apapọ n gbiyanju agbara wọn, ọna kekere ti awa naa si mọ ree lati ran awọn eleto aabo wa lọwọ. A n fi asiko yii dupẹ lọwọ awọn eleto aabo wa lori awọn iṣẹ ti wọn n ṣe lati ri i pe a n sun ni alẹ.

Nigba to n fi idunnu rẹ han, ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Mohammed Bagega, dupẹ lọwọ ijọba Kwara fun iranlọwọ wọn, to si ṣeleri wi pe awọn ko ni i ja ijọba atawọn araalu kulẹ lori eto aabo ipinlẹ naa.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI