Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Gbogbo eto lo ti pari bayii fun gbogbo awọn ara ilu Abẹokuta ati agbegbe rẹ lati bẹrẹ si i jẹ anfaani omi ẹrọ to ja geere lai ni idaduro kankan mọ.
Laipẹ yii ni ijọba ipinlẹ Ogun labẹ gomina Dapọ Abiọdun kede sita wi pe iṣẹ ti pari lori atunṣe ileeṣẹ to n ri sọrọ ipese omi nilu Abẹokuta ati agbegbe ẹ, iyẹn Arakanga Water Works to wa ni Arakanga nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta.
Oludamọran pataki fun Gomina lori ọrọ ipese omi ati iṣẹ akanṣe, Onimọ-ẹrọ Adekunle Ọtun lo sọ eyi di mimọ ninu ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii wi pe awọn ti pari gbogbo atunṣe to yẹ lati ṣe, to si lo o ku diẹ kawọn bẹrẹ si i pin omi ẹrọ to ja geere fun gbogbo awọn araalu.
O ni ki i ṣe ilu Abẹokuta nikan ni wọn yoo ti maa jẹ anfaani yii bi ko ṣe pe nigba tawọn ba pari atunṣe awọn irinṣẹ omi to n gbe omi kaakiri awọn ẹkun mẹta naa tan, awọn ara agbegbe naa yoo bẹrẹ si i jẹ anfaani ti wọn.
Siwaju si i lo jẹ ka mọ pe ọdun to kọja ti i ṣe 2020 lawọn bẹrẹ atunṣe yii, eyi to lo fa a kawọn ti omi naa pa, ati pe ni bayii, awọn atunṣe naa ti pari, ki omi bẹrẹ si i yọ lo ku.
Ki i ṣe ahesọ tabi irọ wi pe awọn ara Abẹokuta ati agbegbe ti jiya omi ẹrọ gidi lati bi ọdun meloo kan sẹyin, eyi to jẹ ki wọn maa wa gbogbo ọna lati ori mu, bawọn kan ṣe n mu omi odo, lawọn kan n mu omi kanga, tawọn kan si n mu ẹsun omi to n jade lẹgbẹ kọta kaakiri ilu Abẹokuta agbegbe ẹ.
Diẹ ree lara awọn fọto atunṣẹ ileeṣẹ omi ẹrọ naa to wa ni Arakanga nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun
No comments:
Post a Comment