Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti tẹ gbajugbaja oṣere tiata kan pẹlu oriṣiriṣi ibọn lọwọ, ti wọn si ni iwadii ti bẹrẹ lori ẹ.
Mike Omoruyi lorukọ oṣere tiata naa, ẹni ọdun mẹtadinlogoji si ni pẹluu. Agbegbe Obiaruku si Umuebu to wa nipinlẹ Delta la gbọ pe wọn ti da Mike duro pẹlu mọto ẹ, ti wọn si ba oriṣiriṣi ibọn nibẹ.
Ṣe ni iṣẹlẹ naa dabi fiimu lọjọ ti a n sọ yii, nigba ti wọn lawọn ọlọpaa da Mike duro, ti wọn si n beere oriṣiriṣi ọrọ lọwọ ẹ, ko to di pe wọn yẹ ẹyin mọto ẹ wo, nibi ti wọn ti ba awọn ibọn naa.
Nigba ti wọn ba awọn ibọn naa, Mike jẹ ko ye wọn pe oun ṣẹṣẹ lọ ya a ni, ati pe fiimu lawọn fẹ fi awọn ibọn naa ya, to si ni oju ọna oko ere loun n lọ.
O ni ọwọ oloye kan, Otuya Josiah, ẹni ọdun mẹdinlọgọta loun ti ya awọn ibọn naa lati fi ṣe fiimu.
Wọn darukọ awọn ibọn naa gẹgẹ bi i Lar rifle kan, fabricated AK-47 kan, air rifle kan, pump action kan, English double barrel kan, ati ibọn iṣere meji.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Ari Muhammed Ali nigba to n sọrọ sọ pe iwadii awọn ti n lọ, ati pe ọwọ tẹ Josiah to ya Mike lawọn ibọn yii, to si lawọn ti n beere ibi to ti ri wọn.
Ẹgbẹrun lọna aadọta naira la gbọ pe Mike fi ya awọn ibọn naa lọwọ Josiah.
No comments:
Post a Comment