Ijọba apapọ orileede yii ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ olori ajijangbara ilẹ Biafra ti wọn pe ni Idigenous People of Biafra, IPOB, Nnamdi Kanu.
Minisita fun ọrọ eto idajọ lorilẹede Naijiria, Abubakar Malami lo sọ eyi di mimọ lonii, ọjọ Isẹgun, Tusidee, oni.
AWIKONKO gbọ pe ọsẹ to kọja yii lọwọ tẹ Kanu niluu oyinbo to wa lọhun.
Ijọba orileede yii la gbọ pe wọn lẹdi apo pọ pẹlu awọn agbofinro ilẹ Amẹrika ti wọn n pe ni Interpol, ti wọn fi rọwọ to.
Bi wọn ṣe muu la gbọ pe wọn ti gbe e pada wa si Naijiria lọjọ Sande ijẹta.
A gbọ pe wọn yoo fi oju rẹ ba ile ẹjọ, koda, wọn tun ti ka oriṣiriṣi ẹsun mi in si lẹsẹ to ni i ṣe pẹlu idaluru, ati lilo ibọn lọna ti ko ba ofin mu.
No comments:
Post a Comment