Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii ati itọpinpin lati ri baale ile kan, Lukman gba silẹ kuro lọwọ awọn ajinigbe, ti wọn ji gbe lọsẹ to kọja yii.
Awọn ajinigbe naa ti pa iyawo Lukman, Hawawu to wa ninu oyun ko to di pe wọn ji oun funra rẹ gbe salọ, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
"Opopona Ọffa si Ojoku la gbọ pe awọn ajinigbe naa ti ṣọṣẹ buruku yii lọjọ Aiku, Sannde ana." Ọkasanmi Ajayi, alukoro fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa ṣalaye.
Ọkasanmi sọ siwaju pe "Otitọ niṣẹlẹ ọhun, ileeṣẹ wa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lọna igbalode lati ri i pe a gba ọkunrin naa silẹ lọwọ awọn ajinigbe, gẹgẹ bi ọga wa, Mohammed Lawal Bagega ti paṣẹ rẹ."
AWIKONKO gbọ pe nitori wi pe Hawawu da awọn ajinigbe naa mọ lo jẹ ki wọn yinbọn pa a danu, ki aṣiri wọn ma ba a tu.
Wọn ni foonu ni Lukman n ta ninu ọja Owode to wa ni Ọffa. Awọn araalu naa la gbọ pe wọn ti n fẹhonu han bayii.
Iroyin to tun ṣẹṣẹ tẹ wa lọwọ bayii ni pe awọn ajinigbe naa ti n beere miliọnu lọna ogun naira, ki wọn to le fi Lukman silẹ lahamọ wọn.
No comments:
Post a Comment