Aye le o! Gbajumọ Pasitọ lu iyawo ẹ pa, lo ba sin oku ẹ sinu ọgba ṣọọṣi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 16, 2021

Aye le o! Gbajumọ Pasitọ lu iyawo ẹ pa, lo ba sin oku ẹ sinu ọgba ṣọọṣi


Aṣiri gbajumọ ayederu Pasitọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Enoch lo ti tu bayii lori bo ṣe lu iyawo rẹ pa, to si tun lọ sin oku rẹ sinu ayika ọgba ṣọọṣi ẹ.

Enoch ni wọn lo ni ṣọọṣi Omega World Global Ministries to wa lagbegbe Ikot Abasi, Okon Clan nijọba ibilẹ Eket, ipinlẹ Akwa Ibom.

Bawọn kan ṣe n sọ pe ṣe ni Enoch pa iyawo ẹ lati fi ṣẹṣo, bẹẹ lawọn kan n sọ pe oogun awọro lo lo iyawo rẹ fun, tawọn kan si n sọ pe ọrọ rẹ ki i ṣoju lasan, nitori ti wọn lo lọwọ aye ninu.

A gbọ pe bi iyawo Enoch ṣe poora lo n ya awọn lẹnu, gbogbo bi wọn si ṣe n beere lọwọ ọkunrin naa pe iyawo rẹ n kọ, ni wọn lo n sọ pe ko si nile.

Irin ajo ni wọn sọ pe Enoch n sọ fawọn eeyan wi pe iyawo oun lọ. Pupọ awọn to si n pe ẹrọ ibanisọrọ obinrin ọhun ni wọn n sọ pe ko lọ fun ọsẹ meji gbako, eyi gan an lo fu awọn eeyan lara.

Igbagbọ ti wọn lawọn eeyan agbegbe naa ko ni ninu Enoch lo jẹ ki awọn ọdọ agbegbe naa dide lati ṣe iwadii ibi ti obinrin naa wa. Idi gan an ree ti wọn fi lọ fi ọrọ naa to olori egbe eleto aabo OYC, Kọmureedi Effiong Johnson leti.

Ninu iwadii wọn ni wọn ti mọ pe Enoch mọ nipa bi iyawo rẹ ṣe poora lojiji, ti wọn si lọ gbe e. Bi wọn ṣe gbe e ni wọn ti fọrọ wa a lẹnu wo, to si pada jẹwọ pe ṣe loun pa a, toun si ri oku rẹ mọlẹ.

Iya ko to lilu ni wọn fi tiẹ ṣe nigba ti aṣiri tu sita pe ṣe lo pa obinrin naa, to si tun ṣe oku rẹ loku oru. Funra rẹ lo mu awọn eeyan lọ sibi to sin iyawo rẹ si.







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI