Bo tilẹ jẹ pe ki ipade naa to o waye ni wọn lawọn oloye ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara, paapaa lẹka ijọba ibilẹ Ọffa ko ti fọwọ si i, ṣugbọn ti wọn sọ pe eti ikun ti wọn kọ si ikilọ lo fa wahala nla.
Ana ti i ṣe Sande, Aiku lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC naa ṣe ipade kan ti wọn fi ṣe iwọde, eyi ti wọn sọ pe kọmiṣanna fọrọ omi, Ọnọrebu Waheed Fẹmi Agbaje lo ṣagbatẹru ẹ niluu Ọffa, ipinlẹ naa.
Ibi ti wọn ti n ṣe iwọde alaafia naa la gbọ pe awọn tọọgi kan ti ya lu wọn, ti wọn si da eto naa ru mọ wọn lọwọ. Pupọ awọn eeyan la gbọ pe wọn farapa yannayanna.
Bawọn kan ṣe n sọ pe wahala naa ko ṣẹyin bi Sẹneto Lọla Ashiru ati Fẹmi Agbaje ṣe n fẹẹ fi agba han ara wọn, bẹẹ lawọn kan n sọ pe awọn agbaagba ẹgbẹ naa lo n fa wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ.
Bawọn kan ṣe n sọ pe wahala naa ko ṣẹyin bi Sẹneto Lọla Ashiru ati Fẹmi Agbaje ṣe n fẹẹ fi agba han ara wọn, bẹẹ lawọn kan n sọ pe awọn agbaagba ẹgbẹ naa lo n fa wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ.
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ naa to le ni ẹgbẹrun lọna ogun lawọn ko ṣe ẹgbẹ APC mọ, iyẹn niluu Ilọrin lọjọ Satide to kọja.
AWIKONKO gbọ pe bi wahala naa ṣe bẹ silẹ lawọn eeyan ti bẹrẹ si i leri ogun sira wọn, to si mu ki ẹru maa ba pupọ awọn araalu wi pe ogun n bọ.
Bi ibọn ṣe n ro lọtun, lo n ro losi lọjọ, nibi tawọn meji ti fara gba ọta. Awọn meji naa ni wọn lọmọ ẹyin Ọnọrebu Agbaje ni wọn.
Awọn ẹlẹyinju aanu la gbọ pe wọn sare gbe awọn fara gbọta naa lọ sọsibitu fun itọju, ko to di pe awọn ọlọpaa debẹ lati pana ọrọ naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti wa a sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ awọn to ṣiṣẹ buruku naa, to si ni gbogbo wọn ni wọn yoo foju winna ofin bọwọ ba tẹ wọn.
No comments:
Post a Comment