Ọnarebu Sikiru Ogundele, to jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun pe ajọ to n ri si eto ibo ijọba ibilẹ iyẹn OGSIEC, fẹẹ da nnkan ru mọ wọn loju ru, nitori igbesẹ ti wọn gbe latigba ti wọn ti bẹrẹ.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ lonii, o ni titi di akoko to n sọrọ yii ko si wahala kankan ninu ẹgbẹ naa tawọn si ti n gbọ ara wọn lagbọye.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fawọn ajọ OGSIEC, eyi ti Ọgbẹni Babatunde Ọṣibodu, jẹ alaga wọn lo ara wọn lati da wa silẹ lori awọn oludije wọn fun ibo ijọba ibilẹ ati kanselọ to n bọ lọna.
O fikun ọrọ ẹ pe lati le mu awọn eeyan daju gbogbo nnkan tawọn OGSIEC beere fun lawọn ti fi sọwọ si wọn, lati ile -ẹgbẹ naa lapapọ ati lọya wọn iyẹn Ricky Tarfa& Co, eyi to le tọ wọn sọna.
Pẹlu gbogbo ẹ naa, o ni ajọ OGSIEC , tun gbọna alukọrọmi lati fi ṣe ifẹ inu wọn.
O ni eyi fi han daju pe ajọ OGSIEC n ṣiṣẹ pọ pẹlu Gomina Dapọ Abiọdun lati le rii pe gbogbo ipinlẹ di ẹyọ kan ṣoṣo, tawọn ko si ni gba fun wọn.
O ni awọn ti wa ṣetan lati maa tu aṣiiri ajọ eleto ibo ọhun sita faraye ri ati pe awọn ko nigbagbọ ninu wọn.
No comments:
Post a Comment