Abdulrazaq ṣe iranwọ nla fawọn ara ọja Oro, bẹẹ lo tun ṣe ileri fawọn ara ọja Ipata - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 6, 2021

Abdulrazaq ṣe iranwọ nla fawọn ara ọja Oro, bẹẹ lo tun ṣe ileri fawọn ara ọja Ipata


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti fun awọn ti ṣọọbu ati dukia wọn jona ninu ọja Oro to wa nijọba ibilẹ Irẹpọdun ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni owo nla lati fi bẹrẹ ọja wọn pada.

Miliọnu mẹta naira la gbọ pe Gomina AbdulRazaq gbe kalẹ lorukọ ijọba ipinlẹ naa lati fi ṣe iranlọwọ nla yii, tawọn eeyan si n dupẹ lọwọ rẹ.

Nigba to n gbe owo naa kalẹ fawọn eeyan l'Aafin Oloro tilu Oro, akọwe ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ iṣẹlẹ pajawiri, iyẹn Kwara State Emergency and Relief Service, Arabinrin Motunrayọ Adaran sọ latigba ti ijamba naa ti ṣẹlẹ ni ijọba ti n wa ọna lati fi ran awọn to padanu dukia ati ọja wọn lọwọ.
 
Adaran sọ pe bo tilẹ jẹ pe owo naa ko to nnkan to le da gbogbo ikolọ wọn pada, ṣugbọn yoo gbe diẹ ninu bukata ohun ti wọn padanu lati fi bẹrẹ ọja mi in, ati pe lati le pada bẹrẹ ọja ti wọn n ta ni, to si ni ẹdun ọkan lo jẹ fun ijọba.
 
Babalọja ati iyalọja ọja naa, Ọgbẹni Tijani Sodiq ati Arabinrin Mulikat Jimọh dupẹ gidigidi lọwọ gomina AbdulRahman AbdulRazaq fun bo ṣe mu ileri rẹ ṣẹ, to si lawọn ko le gbagbe rẹ titi ayeraye.
 
Ninu iroyin mi in to jọ ara wọn ni gomina AbdulRazaq tun ti ba awọn ara ọja Ipata kẹdun lori bi ọja naa tun ṣe jona di eeru, tawọn dukia olowo iyebiye si ba a lọ pẹluu.
 

Igbakeji gomina, Ọgbẹni Kayọde Alabi nigba to n gba ẹnu goomina sọrọ sọ pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati ṣe iranlọwọ to ba yẹ fawọn to padanu ọja ati dukia wọn sinu ijamba naa.

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI