Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede sita pe awọn ti ri ọmọ kekere kan t'ọjọ ori ẹ ko ti i ju oṣu mẹfa lọ he l'agbegbe Amuwo-Ọdọfin n'ipinlẹ naa.
Ọjọ Iṣẹgun ti i ṣe Tusidee la gbọ pe wọn ri ọmọ naa t'ẹnikẹni ko ti i mọ awọn obi rẹ d'asiko ta pari iroyin yii ni 24B, Plot 3006, adugbo Rafiu Babatunde Tinubu, Amuwo Odofin.
A gbọ pe l'oju ẹsẹ t'awọn ẹlẹyin aanu ti ri ọmọ naa ni wọn ti ranṣẹ s'awọn ọlọpaa, ti wọn si l'awọn ọlọpaa naa ti gbe ọmọ yii lọ s'ile awọn ọmọ orukan, iyẹn Juvenile and Women Centre (JWC) to wa ni Alakara l'Ekoo.
No comments:
Post a Comment