'Ere ni mo fi n ṣe, ẹ ṣ'aanu mi' lọrọ ẹbẹ to n jade lẹnu gendekunrin kan, Ọmọtayọ Ọlaiya ti wọn lo n f'ibọn d'ẹruba ọkan lara àwọn ará àdúgbò kan nilu Eko nigba tọwọ ọlọpaa tẹ ẹ.
Wọn ni inu mọṣalaṣi Ansarudeen to wa l'adugbo Bọla, Ebute-Metta nilu Eko ni Ọmọtayọ ti yọ ibọn lọ ọ ba Ọlatunji Ṣakirat Mayo, ti wọn sì lo n dunkooko pé òun yóò pa a danu.
Awọn to wa nitosi la gbọ pé wọn gba Ṣakirat silẹ lọwọ ẹ, to fi sáré gba teṣan ọlọpaa Denton lọ láti fi ẹjọ sun.
B'awọn ọlọpaa ṣe gbọ ni wọn ti sáré lọ síbẹ̀, ti wọn sì gbe è lọ teṣan wọn lati f'ọrọ wa a lẹnu wò.
Ibọn ilewọ naa ti wọn pe orúkọ rẹ ní Brownie Pistol la gbọ pé wọn bá lọwọ ẹ bi wọn ṣe de'bẹ, foonu kan ti wọn pe ni Motorola walkie-talkie naa tun wa lọwọ ẹ lasiko yii.
Nigba ti wọn n beere ibi ti Ọmọtayọ ti ri ibọn naa, o ni ọwọ ọrẹ oun kan to n jẹ Taiwo loun ti ra a ni Ikorodu ninu oṣù kọkànlá ọdún tó kọjá. O ni ẹgbẹrun lọnà ọgọrin naira loun ra a lọwọ ẹ nígbà náà.
Ọgá ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti pàṣẹ pé ti sọ pé kí iwadii tubọ tẹsiwaju lori ẹ, pàápàá lori awọn to n lo ibọn lọnà tí kò bá òfin mu.
No comments:
Post a Comment